NNPC: Awọn alagbata epo lo wa nidi bẹntiroolu to wọn

Awọn eeyan to fun epo nileepo kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Lati osu kejila ọdun 2017 ni orilẹede Naijiria ti wa ninu wahala aisi epo

Kii ṣe iroyin mọ pe awọn eeyan orilẹede Naijiria ti n ba ọwọngogo epo bẹntiroolu finra lati nkan bii oṣu mẹta sẹyin, eleyi ti o ti fa oniruuru inira, ọwọgogo ọja ati irinna fun awọn eeyan orilẹede naa.

Amọṣa, ajọ to wa nidi ọrọ epo rọbi lorilẹede Naijiria, NNPC ti wọ ara rẹ mọ ninu ẹbi wahala ọwọngogo epo nibẹ.

Ọgbẹni Ndu Ughamadu to jẹ olori ẹka alukoro ni ajọ naa ni bi eto pinpin epo kaakiri orilẹede Naijiria se n jo lawọn ibikan lo n ṣokunfa ọwọngogo epo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Wahala aisi epo ti koba ọrọ aje ọpọlọpọ ọmọ Naijiria

Ọgbẹni Ndu Ughamadu di ẹbi ọwọngogo epo ru awọn alagbata epo lasiko ti o n fesi si ehonu ẹgbẹ ajafẹtọ araalu kan ti wọn pe ni 'OurMumuDonDo' to se iwọde wa si olu ileeṣẹ ajọ NNPC nilu Abuja ti ṣe olu ilu Naijiria.

Olori ẹka alukoro ni ajọ NNPC naa ni awọn alagbata epo lo n dari epo to yẹ fun elo awọn ọmọ orilẹede Naijiria lọ si awọn orilẹede miran to yii ka.

"Ajọ NNPC nikan lo laṣẹ lati ko epo rọbi wọ orilẹede Naijiria ati lati maa fọ epo labẹle eleyi to ti ṣe daadaa lati rii pe epo naa to fun elo araalu.

"Amọṣa, iwa ibajẹ awọn oni fayawọ epo ti wọn n dari epo to yẹ ki araalu lo lọ si awọn orilẹede miran jẹ iṣoro nla."

Oríṣun àwòrán, @OurMumuDonDo

Àkọlé àwòrán,

Ọpọlọpọ iwọde lo ti waye lori ọwọngogo epo lorilẹede Naijiria

Gbajugbaja olorin ni, Charles Oputa ti ọpọlọpọ eeyan mọ si charlie boy lewaju ikọ 'ourmumudondo' lọ si olu ileesẹ ajọ elepo rọbi lorilẹede Naijiria, NNPC fun iwọde alaafia kan lati pe akiyesi si wahala ọwọngogo epo bẹntiroolu to n waye kaakiri orilẹede naa.

Ẹgbẹ ajafẹtọ araalu ti wọn pe ni 'our mumu don do' jẹ agbarijọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati origun gbogbo ti wọn paraps lati ja fun itaniji lori titẹẹ mọ awọn aṣiwaju leti lori ojuse wọn ati lati lee rii wi pe isejọjọba to dan mọran gbilẹ lẹka isejọba gbogbo.

Lasiko iwọde rẹ ọhun, ẹgbẹ naa pa aroko ikilọ ransẹ si awọn alasẹ ajọ NNPC lati tete wa ojuutu si bi ila awọn eeyan to nto fun epo kaakiri orilẹede Naijiria se n gun sii lojoojumọ ki o to di wipe wọn tan awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni suuru.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Oniruuru ọna lawọn eeyan n gba lati ri epo si ọkọ wọn

Ẹgbẹ naa ni iwọde naa se pataki lati lee jẹ ki o di mimọ fun ajọ NNPC atawọn alẹnulọrọ gbogbo lẹka epo rọbi lorilẹede Naijiria wipe gulegule wahala aisi epo bẹntiroolu ti mu ọkẹ aimoye isoro ati inira ba awọn awọn ọmọ orilẹede Naijiria.

Ninu ọrọ rẹ, Charly boy ti bi awọn ileepo se n fi ojojumọ wa ni titipa nitori aisi epo lati ta fun araalu tabi bi awọn ọkọ se n to kalẹ fun ọpọlọpọ wakati lati ra epo nitori ọwọngogo rẹ ti fẹ maa tan awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni suuru.

"Fun oṣu mẹta bayii lawọn ọmọ orilẹede Naijiria ti n farada wahala ọwọngogo epo eleyi to ti fa afikun owo ori ọja, ọkọ pẹlu wahala fifi ọpọlọpọ akoko sofo lori tito kaakiri ile epo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọpọ igba si ni ajọ NNPC ati awọn alagbata epo ti takoto ọrọ sirawọn lori ọrọ epo loriẹede Naijiria

"Awa ẹgbẹ 'OurMumuDonDo' ti pinnu lati dide lati lee mu aarọ, ajọ NNPC atawọn eeyan miran ti ọrọ kan lẹka epo rọbi tet wa nkan se si ọrọ naa.

"O yẹ ki wọn tete wa wọrọkọ fi ṣada bayii lati fopin si iṣoro to n koju awọn ọmọ orilẹede Naijiria, kii ṣe Abuja nikan, ṣugbọn jakejade orilẹede Naijiria."

Awọn ẹgbẹ ajafẹtọ miran bii 'the Concerned Nigerians' ati 'Coalition in Defence of Nigerian Democracy' naa kopa ninu iwọde yii.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: