Buhari yoo ṣe'pade pẹlu Ọbasanjọ, IBB ati Jonathan lori ọrọ aabo

Buhari, Obasanjọ ati IBB

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Obasanjọ ati IBB lo lewaju awọn ọrọ atako si Buhari lẹnu ọjọ mẹta yii

Ireti wa wipe aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari yoo ṣe ipade pọ pẹlu awọn olori orilẹede yii nigbakanri lọjọọbọ nibi ipade igbimọ olubadamọran to ga julọ lorilẹede Naijiria nilu Abuja.

Ipade yii ni yoo jẹ ẹlẹẹkẹta ti aarẹ Buhari yoo maa ko jọ lati ọdun 2015 to ti de ori ipo.

Lara awọn ti ireti wa wipe yoo farahan nibi ipade yii ni awọn aarẹ alagbada to ti jẹ lorilẹede Naijiria nigbakanri, Alhaji Shehu Shagari, Oloye Olusegun Obasanjo ati Goodluck Jonathan.

Awọn miran ni awọn olori ijọba ologun bii Ọgagun Yakubu Gowon, Ibrahim Babangida, Abdulsalami Abubakar pẹlu olori ijọba fidihẹẹ, Oloye Ernest Shonekan.

Igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo pẹlu yoo wa nibẹ ati aarẹ ile aṣofin agba orilẹede Naijiria Bukola Saraki; olori ileegbimọ asofinsoju, Yakubu Dogara; pẹlu gbogbo awọn adajọ agba orilẹede Naijiria nigbakanri tofimọ awọn gomina ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa nibẹ pẹlu amofin agba Abubakar Malami.

Awọn wahala ipaniyan awọn darandaran fulani kun ara awọn ohun ti ireti wa wipe yoo wa fun ijiroro nibi ipade naa.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: