Obasanjo, Fayose ṣe'pade pẹlu aare Buhari l'Abuja

Buhari ati Ọbasanjọ nki ara wọn Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán Ọbasanjọ ti kọ lẹta si Buhari eleyi to di gbajugbaja kaakiri agbaye

Ipade igbimọ olubadamọran to ga julọ lorilẹede Naijiria ti bẹrẹ nilu Abuja, pẹlu aarẹ tẹlẹri Olusẹgun Obasanjọ ati gomina ipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose.

Aarẹ Muhammadu Buhari lo n dari ipade naa eleyi ti yoo jẹ ẹlẹẹkẹta ti aarẹ Buhari yoo maa ko jọ lati ọdun 2015 to ti de ori ipo.

Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán Fayose to jẹ ọkan gboogi ninu awọn alatako aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari

Lara awọn to wa nibi ipade naa ni wipe yoo farahan nibi ipade yii ni Oloye Olusegun Obasanjo, gomina ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayose atawọn gomina ipinlẹ lorilẹede Naijiria.

Bakannaa ni Igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo pẹlu wa nibẹ.

Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán Awọn aarẹ igbakanri, adajọ agba igbakanri ati awọn gomina ipinlẹ wa lara Igbimọ olubadamọran to ga julọ lorilẹede Naijiria

Ireti wa wipe awọn wahala ipaniyan awọn darandaran fulani yoo kun ara awọn ohun ti ireti wa wipe yoo wa fun ijiroro nibi ipade naa.

Ẹkunrẹrẹ iroyin n bọ laipẹ.