Ijinigbe Yobe: Ile iṣẹ ologun doola ẹmi akẹkọ mẹ́rìndínlọ́gọ́rin ni Yobe

Awọn akẹko ile iwe ni Yobe

Oríṣun àwòrán, Yobe State Government

Àkọlé àwòrán,

Ko daju pato iye awọn akeko ti wọn ji gbe.

Ijọba ipinlẹ Yobe ti kede pe ile iṣẹ ologun Naijiria ti doola ẹmi awọn ọmọ akẹẹkọ obirin ile ẹkọ Government Girls Science Technical College, Dapchi ti Boko Haram jin gbe lalẹ ọjọ aje.

Ninu atẹjade kan lati ọdọ Abdullahi Bego to jẹ agbẹnusọ fun Gomina ipinlẹ naa, o ni wọn gba awọn ọmọbirin naa la lẹgbẹ Geidam, ilu kan to sun mọ bode pẹlu ipinlẹ Borno.

Akẹkọ mẹ́rìndínlọ́gọ́rin ni wọn doola, ti wọn si ri oku mẹji ninu wọn.

O kere tan akẹko mẹtala ni wọn o ti ri.

Nigba ti o'n ba awọn oniroyin sọrọ, Babagana Umar to jẹ obi ọkan lara awọn ọmọ ti wọn doola, sọ wi pe ''Orin ọpẹ gba ẹnu wa bi wọn ti ṣe da awọn ọmọ wa pada. Oun to bani ninu jẹ ni wi pe awọn meji ku ninu wọn. A o si gbọ alaye bi wọn ti ṣe ku"

Àkọlé àwòrán,

Naijiria ko gbagbe iṣẹlẹ Chibok nibi ti Boko Haram ti ji awọn ọmọ ile ẹkọ obirin

Ṣaaju ni aarẹ Muhammadu Buhari ti paṣẹ fun awọn ologun ati ọlọpaa lati rii wi pe wọn gba akoso nnkan ni ile ẹkọ naa.

Aṣẹ na waye lẹyin nigba ti iroyin gbalẹ pe ọmọ ile ẹkọ mẹ́rìndínlọ́gọ́rin ni Boko Haram ji gbe lọjọ aje.

Ẹyinwa igba naa ni minisita meji labẹ ijọba yii ṣe abẹwo si ile ẹkọ naa nirọlẹ ọjọbọ.

Awọn ọmọ orilẹede Naijiria ko gbagbe iṣẹlẹ Chibok nibi ti Boko Haram ti ji awọn ọmọ ile ẹkọ obirin ọ̀tàlénígba le mẹwaa gbe lọdun 2014.

Niṣe ni iṣẹlẹ naa mu ki oju awujọ agbaye ṣi si wahala idunkokomọni Boko Haram ti o ti to ọdun mẹsan to bẹrẹ bayi.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: