Bawo ni o ṣe mọ ede rẹ si?

Aworan idanwo
Àkọlé àwòrán Ajọ iṣọkan awọn orilẹede lo ya ọjọ naa s'ọtọ lati ṣe igbelarugẹ fun oniruuru ede

Ọjọ kọkanlelogun oṣu keji ọdọdun ni ayajọ ọjọ ede abinibi lagbaye.

Ajọ iṣọkan awọn orilẹede lo ya ọjọ naa s'ọtọ lati ṣe igbelarugẹ fun oniruuru ede to wa l'agbaye. Kini ipa ti gbigbọ ede ju ẹyọkan lọ n ko lori ede abinibi?

Gẹgẹbi ọmọ ilẹ kaarọ, o jiire, bawo ni imọ rẹ ṣe to nipa ede rẹ.

Akọle ajọdun ti ọdun yii ni: "Ọjọ awọn ti wọn gbọ ede ju oyọkan lọ."

Idanwo kan ni yii. Ẹ tẹ, ki ẹ gbiyanju idanwo na wo ki ẹ le mọ boya ẹ dangajia ninu ede Yoruba tabi o ku diẹ k'ato.

Bi ẹ o ṣe ṣe idanwo naa niyii: To ba jẹ wipe foonu l'ẹnlo, ẹ tẹ Yoruba to wa ni apa alafia, lẹyin naa ki ẹ tẹ itumo rẹ ni ede Gẹẹsi ni apa ọtun.

Lori kọmputa, ẹ kọkọ tẹ Yoruba ni apa alafia ki ẹ to tẹ itumọ rẹ ni apa ọtun.