BBC ṣe'filọlẹ ami ẹyẹ Komla Dumor f‘ọdun 2018

Komla Dumor
Àkọlé àwòrán Ilu Accra tii ṣe olu ilu orilẹede Ghana ni wọn ti n sefilọlẹ ami ẹyẹ tọdun yi

Ileeṣẹ BBC nwa awọn irawọ to ṣẹṣẹ ndidelẹ ninu iṣẹ akọroyin nilẹ Afrika fun ami ẹyẹ Komla Dumor tileeṣẹ BBC lagbaye.

Awọn akọroyin jakejado ilẹ Afrika ni wọn npe lati kopa ninu ami ẹyẹ yii, eyi ti afojusun rẹ wa lati sawari ati agbelarugẹ awọn irawọ tuntun latilẹ Afrika.

Ẹni to ba yege yoo lo osu mẹta ni olu ileesẹ BBC nilu London, yoo ni ọpọ imọ kikun ati iriri.

Deede aago mejila ku isẹju kan loru ọjọ kẹtalelogun osu kẹta ọdun 2018 ni ikọwe beere lati kopa ninu ami ẹyẹ naa yoo wa sopin.

Wọn gbe ami ẹyẹ naa kalẹ lati bu ọla fun Komla Dumor, gbajugbaja agbohunsafẹfẹ to dantọ lati orilẹede Ghana, o tun jẹ oniroyin fun ikanni iroyin BBC lagbaye. O sadede dagbere faye lọdun 2014 lẹni ọdun mọkanlelogoji.

Ilu Accra tii ṣe olu ilu orilẹede Ghana ni wọn ti n sefilọlẹ ami ẹyẹ tọdun yi.

A o pese ami ẹyẹ yii fun ẹda kọọkan to tayọ, ti wọn ngbe, ti wọn si tun nsisẹ nilẹ Afrika, ti wọn ko ọgbọn atinuda fun isẹ akọroyin papọ mọ ẹbun to tayọ lori afẹfẹ ati ẹbun to pegede ninu sisọ awọn itan to jẹmọ tilẹ Afrika pẹlu ilakaka ati aayan lati di irawọ ọjọ ọla.

Yatọ si pe ẹni to ba yege lati gba ami ẹyẹ naa yoo lọ lo akoko kan nibujoko ileesẹ BBC nilu London, bakanaa ni onitọun yoo tun se abẹwo wa si Afrika lati wa kọ iroyin-ti wọn yoo si se alabapin iroyin naa jakejado ilẹ Afrika ati lagbaye.

Àkọlé àwòrán Ẹni to gba ami ẹyẹ naa lọdun 2017 Amina Yuguda kọ iroyin nipa awọn isẹlẹ ayika lasiko to wa pẹlu BBC

Awọn eeyan to ti gba ami ẹyẹ Komla Dumor tẹlẹ ni Nancy Kacungira lati orilẹede Uganda, Didi Akinyẹlurẹ lati orilẹede Naijiria, ati Amina Yuguda, lati orilẹede Naijiria bakanaa.

Fun isẹ akanse rẹ, Amina kọ iroyin lati orilẹede Uganda lori Ewu to n koju adagun odo Victoria, tii se adagun odo to tobi julọ pẹlu omi ọtun nilẹ Afrika, eyi tawọn onimọ ijinlẹ sayẹnsi sekilọ pe o lee maa ku lọ.

Amina ni: "Gẹgẹ bii ẹni to gba ami ẹyẹ Komla Dumor tileesẹ iroyin BBC lagbaye fọdun 2017, o dabi ẹnipe ibẹrẹ isẹ ti mo yan laayo niyi lo se ri lara mi. Lati de ipele isẹ akọroyin lagbaye, ki n jẹ ilu mọọka lagbaye, o dabi ẹnipe mo ti de ibi giga ni.

"Lasiko ti mo fi ngba idanilẹkọ, mo kọ nipa pataki sisọ otitọ, kikọ iroyin lai segbe sibikan ati fifun igun kọọkan ni anfaani ọgbọọgba, ti mo si tun ni iriri lori baa se lee ni oju inu to se iyebiye lati kọ iroyin nipa ilẹ Afrika, lọna ti yoo fi fa oju awujọ agbaye mọra.

"Ori wa wu nipa ọna ti Komla gba soju ilẹ Afrika ni awujọ agbaye, mo si ri ara mi bii ẹni taa bu ọla fun pẹlu sise iranwọ lati mu ki ogun rere yi tẹsiwaju."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBBC ṣe'filọlẹ ami ẹyẹ Komlar Dumor

Amina yoo kopa nibi ayẹyẹ ifilọlẹ ami ẹyẹ naa fun tọdun yi, pẹlu Jamie Angus, tii se oludari ileesẹ BBC agbaye.

O sọrọ siwaju ayẹyẹ naa:

"Iyi nla ni fun mi lati wa lorilẹede Ghana, nilu abinibi Komla, laarin awọn mọlẹbi ati ọrẹ rẹ, lati se ajọdun ogun rere to fisilẹ, ki n si tun sawari ogo tuntun mii to tun kan ti yoo bẹrẹ si ni tan ninu isẹ iroyin lati ilẹ Afrika.

"Awọn eeyan mẹtẹẹta to ti gba ami ẹyẹ naa siwaju - Nancy, Didi ati Amina - ti safihan pe akọroyin to ni ẹbun gidi ni wọn, ti wọn si nimọ kikun to fidi mulẹ nipa ilẹ Afrika ati oju inu nipa ọna taa fi lee mu agbega ba ibasepọ wa pẹlu awọn ololufẹ wa.

"A tun ti n foju sọna lati wa awọn akọroyin mii to muna doko lati ilẹ Afrika, ka si ki wọn kaabọ gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu idije ami ẹyẹ Komla Dumor mii, tileesẹ iroyin BBC lagbaye."

  • Lati mọ boya o kaju ẹ, lati kopa ninu idije yi, ẹ tẹ oju opo yii
  • Bakanna lẹ lee polongo ikede yi lori awọn opo ikansira ẹni lori itakun agbaye pẹlu ami idamọ yii #BBCKomlaAwards.