2018 Jamb: Awọn akẹkọ fọnmu lori iforukọsilẹ

Image copyright @JAMB
Àkọlé àwòrán Ajọ JAMB sun ọjọ iforukosilẹ idanwo UTME siwaju lati ọsẹ meji sẹhin

Ọgọọrọ awọn akẹkọ to n gbaradi fun idanwo asewọle sile ẹkọ giga, UTME tọdun yii ti fẹhọnu han lori bii ajọ Jamb se ti oju opo ti wọn ti n forukọ silẹ fun idanwo UTME tọdun yii.

Awọn akẹkọ naa ni wọn yabo agbegbe Bariga nilu Eko, pẹlu paali ti wọn kọ ẹhọnu wọn si lọwọ wọn, ti wọn si n sọ wipe ọpọlọpọ awọn ni ko tii forukọ silẹ fun idanwo naa.

Idanwo tọdun yii naa ni yoo waye lọjọ kẹsan si ọjọ kẹtadinlogun osu kẹta, ọdun yii. Sugbọn tawọn to n fẹhọnu han naa sọ wipe, awọn fẹ ki wọn sun siwaju di osu Karun.

Gẹgẹbi ọrọ awọn akẹkọ naa, awọn to kọ idanwo tọdun to kọja, ko tii wọ ile-iwe nitori sunkẹrẹ fakẹrẹ eto ẹkọ lorilẹede Naijiria.

Lara ohun ti paali ti wọn gbe lọwọ yi "ọọdunrun akẹkọ ni ko tii forukọ silẹ fun idanwo UTME", "Awa ko tii setan fun idanwo" ati wipe "Idanwo tọdun yii yoo jasi pabo".

Awọn akẹkọ to bawọn akọroyin sọrọ ni awọn ko tilẹ tii se '"silabọọsi" ti saa yii tan, ati wipe ajọ Jamb n jẹ kawọn san owo toto ẹgbẹrun meji aabọ naira, tawọn ba se asemase kankan lasiko iforukọ silẹ fun idanwo UTME tọdun yii.