Gomina Yobe l'awọn o tii ri awọn ọmọ tan jigbe- Baba ọmọ

Awon omo ile iwe Yobe Image copyright Yobe state government
Àkọlé àwòrán Obi marun daku nigba ti won gbo wipe won ko tii ri

Ọkan lara awọn obi awọn ọmọbinrin ile-iwe Government Girls Science Technical College, Dapchi, nipinlẹ Yobe to wa lẹkun ariwa orilẹede Naijiria, sọwipe gomina Yobe ni awọn ko i tii ri awọn ọmọ ti wọn jigbe lati ọjọ aje.

Kundiri Alhaji Bukar sọ fun BBC wipe nise lawọn obi marun ninu awọn obi naa daku gbọnrangandan lẹyin ti wọn gbọ iroyin naa latẹnu gomina .

Alhaji Bukar gomina Ibrahim Gaidam sọ fun awọn obi ti wọn wa sepade pẹlu rẹ l'ọjọbọ, wipe "awọn ko i tii sawari ọmọ kankan ti awọn agbebọn jigbe ni ile-ẹko wọn, sugbọn awọn ọmọ ogun orilẹede Naijiria n wa wọn kaakiri".

O fikun wipe Gomina naa wipe ko da awọn loju boya ikọ Boko Haram lo ji awọn ọmọ naa gbe abi bẹẹkọ.

Ẹlomiran to wa nibi ipade naa sọwipe ni se ni awọn obi naa bẹrẹ si ni sọrọ odi si gomina naa, lẹyin ti o sọ ọrọ yii, ti wọn si sọọ lokuta pẹlu.

Eleyii n sẹlẹ lai ti pe wakati mẹrinlelogun ti ile-isẹ ọmọogun Naijiria sọwipe awọn ti ri lara awọn ọmọ ti wọn jigbe naa.

Obi kan ti ko darukọ ara rẹ so wipe:: ''L'alẹ ana iroyin sọ wipe awọn ologun ti gba awọn ọmọbirin naa la. Iroyin naa tu wa lara diẹ awọn eeyan si n gb'oriyin fun awọn ijoba fun agba'lẹ awọn ọmọ naa loju ọjọ. A ro wipe wọ yoo ko awọn ọmọ naa wa bawa loni nii.

"Sugbọn lẹyin igba ti gomina naa wa, o lọ si aafin baalẹ abule naa nibi ti awọn obi awọn ọmọ ti wọn sọnu ti pejọ. Nkan ti gomina naa sọ ni wipe ka ni suuru ka f'ọkan balẹ nitori wipe ijọba ko ni aridaju lori wipe wọn ji awọn ọmọbirin naa gbe.

" Ọrọ yi bi awọn eeyan ninu. Ọpọ awọn lo bus'ẹkun, awọn kan tun subu lulẹ. Lẹyin igba naa ni wọn kọlu awọn ọkọ gomina naa, ti wọn lẹ'ko mọ. Awọn ọkọ ti wọn fọ ninu awọn ọkọ rẹ to mẹdogun.''