NPF: N11.1 ni rìbá tí ọlọ́pàá ti gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà

Awọn ọlọpaa Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ni awọn owo gbogbo ti wọn gba naa ni wọn ti da pada fun awọn to ni wọn.

Njẹ o mọ pe owo ẹyin ti ọlọpaa gba lọwọ rẹ atawọn ọmọ orilẹede Naijiria miiran le ni miliọnu mọkanla naira?

Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria gangan funra rẹ lo sọ wi pe, owo to le ni miliọnu mọkanla naira ni wọn ti gba pada lọwọ awọn ọlọpaa gẹgẹ bii owo ẹyin ti awọn ọlọpaa naa gba lọwọ araalu lori oniruuru ẹsun.

Olori ẹka gbohun gbaroye araalu nileeṣẹ ọlọpaa, Abayọmi Ṣogunlẹ lo sọ eyi di mimọ lasiko to fi n ba awọn ọlọpaa sọrọ nilu Oṣogbo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Bakan naa ni ọlọọpa ni awọn oṣiṣẹ rẹ mẹwaa ni wọn ti yọ niṣẹ nitori iwa aṣemaṣe loniran-an-ran

O ni awọn owo gbogbo ti wọn gba naa ni wọn ti da pada fun awọn to ni wọn.

Bakan naa lo ni o le ni ọlọpaa mẹwa ti wọn ti le lẹnu i'sẹ fun ọkan o jọkan iwa ti ko tọ laarin ọdun meji sẹyin.

Ọga ọlọpaa naa ni ko saye iregbe iwakiwa mọ lagbo ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria nitori akitiyan n lọ ni rẹbutu bayii lati ṣe afọmọ orukọ ileeṣẹ naa.

Ọlọpaa nwa ẹni to pa oṣiṣẹ ẹka aabo agbegbe nipinlẹ Eko

Image copyright @AkinwunmiAmbode
Àkọlé àwòrán Olopa n wa eni ti o pa Moshood Bolaji

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kede pe awọn n wa ọkunrin kan ti wọn furasi wipe o ṣe'kupa oṣiṣẹ ikọ ẹka aabo agbegbe nipinlẹ Eko (Lagos State Neighbourhood Safety Corp) ọgbẹni Moshood Bolaji.

Ọgbẹni Bolaji ko agbako iku ni ọjọọbọ ni bii agogo mẹsan abọ ni agbegbe Umunede Bar in Mallam Isah ni Aguda n Surulere nigbati awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun marun kọluu, ti wọn sii ṣee lọ'ṣẹ.

Kọmisọna fun awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Imohimi Edgal ti o ṣe abẹwo si ẹbi Moshood Bolaji ni Aguda-Surulere, sọ pe oun ti paṣẹ fun awọn ọlọpa alakoso kogberegbe (SARS) ati awọn ọlọpaa to n koju iwa ẹgbẹ okunkun lati ṣi wa si agọ ọlọpaa ti o wa ni Aguda-Surulere lẹsẹkẹsẹ.

O tun fun wọn ni aṣẹ lati wọya ija pẹlu awọn ọdaran ọmọ ẹgbẹ okunkun ati lati ṣe awari awọn to da ẹmi Moshood Bolaji legbodo.

Image copyright @AkinwunmiAmbode
Àkọlé àwòrán Moshood Bolaji n ṣisẹ ni agọ ti o wa ni agbegbe Aguda-Surulere

Gẹgẹbi o ṣe ṣalaye, awọn eniyan afurasi mẹta ti wa ni agọ ọlọpa lori ọran naa, ti wọn si nbeere ọrọ lọwọ wọn.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: