CAN: Ipenija aabo ni Naijiria n fẹ ẹjẹ tuntun lawọn ileeṣẹ alaabo

Aarẹ Buhari n se ayẹwo awọn olgun to duro ni iduro ẹyẹ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ CAN kọminu lori kikuna ileesẹ alaabo lati pẹka awọn apanijaye gbogbo to n da omi alaafia orilẹede Naijiria ru

Ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi lorilẹede Naijiria, CAN ti pe fun atunto ileeṣẹ aabo gbogbo lorilẹede Naijiria eleyi ti ko se lẹyin wahala to n de ba eto ọrọ abo paapaajulọ gulegule ipaniyan nihin-lọhun to n waye.

Ninu atẹjade kan to fi sita eleyi to tẹ BBC Yoruba lọwọ, ẹgbẹ CAN ni pẹlu bi nkan se ri bayii lori ọrọ abo lorilẹede Naijiria ti fihan wipe awọn ileesẹ alaabo rẹ nilo awọn ẹjẹ tutu to ni iran tuntun ti o lee da alaafia pada si agbami ọrọ abo orilẹede Naijiria ti ko duro deede ni lọwọlọwọ.

Ẹgbẹ naa koro oju si kikuna ti awọn ileesẹ alaabo n kuna lati pẹka awọn apanijaye gbogbo to n da omi alaafia orilẹede Naijiria ru ki o to di wipe wọn se ọṣẹ wọn.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán CAN ni gbigba awọn osisẹ tuntun fun ipo adari lẹka abo yoo mu iran tuntun ba ọrọ abo

"A ko faramọ aato igbimọ eleeto abo to gaju lorilẹede Naijiria lọwọlọwọ yiieleyi to fi si ọdọ awọn ẹlẹsin kan ati ẹya kan lorilẹede yii. Orilẹede to kun fun ẹya ati ẹsin pupọ ni orilẹede wa, a si n ke si Aarẹ Muhammadu Buhari wipe ko gbọran si ohun ti ofin to de pinpin ipo lorilẹede Naijria, Federal character commission act sọ pẹlu gbogbo awọn iyansipo ati eto rẹ gbogbo."

Bakannaa ni ẹgbẹ CAN tun bu ẹnu atẹ lu bi awọn ọmọde ti ko tii to ibo o di se n forukọsilẹ lati dibo pẹlu ipe si ajọ eleto idibo orilẹede Naijiria, INEC lati tete wa wọrọkọ fi sada lori ọrọ naa eleyi ti wọn ni o n waye kaakiri bayii ti eto iforukọsilẹ awọn oludibo tuntun n lọ lọwọ.

Minisita fun eto iroyin lorilẹede Naijiria, Alhaji Lai Mohammed, ti ni ko sọrọ lori ipe ti ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi lorilẹede Naijiria, CAN pe wipe ki Aarẹ Muhammadu Buhari o se atunto awọn adari ileesẹ ọmọogun rẹ pẹlu awọn ẹjẹ tuntun ti yoo le mu ayipada ati igbona ọkan ba eto abo ati igbesẹ gbigbogun ti awọn adukukulaja.

Alhaji Lai Mohammed ni 'mi o lero wipe mo fẹ sọ ohunkohun lori ọrọ ti CAN sọ.'

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: