Igbimọ majẹobajẹ buwọlu N361 biliọnu f'eto ọgbin

Ọgagunfẹyinti Gowon, Abubakar pẹlu Oloye Ọbasanjọ n jiroro pẹlu Aarẹ Buhari Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán Babangida, Jonathan, Shagari ko si nibi ipade Igbimọ majẹobajẹ to ga julọ lorilẹede Naijiria

Igbimọ majẹobajẹ to ga julọ lorilẹede Naijiria ti buwọlu afikun owo iyasọtọ ti wọn la kalẹ fun idagbasoke eto ọgbin lati igba miliọnu dọla owo ilẹ Amẹrika, ($200 Million) si biliọnu kan dọla owo ilẹ Amẹrika ($1 Billion).

Igbesẹ yii waye nibi ipade igbimọ naa ti wọn ṣe nilu Abuja tii ṣe olu ilu orilẹede Naijiria lọjọọbọ.

Igbimọ majẹobajẹ to ga julọ lorilẹede Naijiria ni igbimọ olubadamọran to ga ju lọ fun aarẹ lorilẹede Naijiria, awọn aarẹ ati adajọ agba to ti figbakanri jẹ pẹlu awọn gomina ipinlẹ ni wọn wa ninu igbimọ yii.

Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán Naijiria n gbe igbesẹ dida ọrọ aje rẹ pada si eyi ti yoo gbe ara le eto ọgbin dipo epo rọbi to gbarale ni lọwọlọwọ

Afikun owo yii ni ireti wa wipe yoo tubọ fẹ eto dida ọrọ aje orilẹede Naijiria pada si eyi ti yoo gbe ara le eto ọgbin dipo epo rọbi to gbarale ni lọwọlọwọ.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lori ijiroro ipade naa, gomina Ibikunle Amosun ti ipinlẹ Ogun ni owo naa yoo di pinpin nipasẹ awọn akanse eto ẹyawo kan ti wọn da pe ni Anchor Borrower Programme atawọn eto ẹyawo miran to ti wa nikalẹ tẹlẹ.

"Banki apapọ orilẹede Naijiria pẹlu ileeṣẹ eto ọgbin ati ileesẹ ọrọ aje pẹlu idokoowo ni ijọba apapọ lo ti n forikori lori ọna ati ran awọn ileesẹ kereje-kereje lọwọ.

" Igbimọ tilẹ daaro wipe o seese ki biliọnu kan dọla owo ilẹ Amẹrika naa o maa to, a n wo nkan bii biliọnu meji dọla. Amọsa biliọnu kan dọla yii ni ibẹẹrẹ rẹ."

Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán Igbimọ majẹobajẹ to ga julọ lorilẹede Naijiria tun buwọlu iyansipo fun awọn ajọ kan

Ni tirẹ gomina ipinlẹ Jigawa, Abubakar Badaru ṣalaye wipe awọn agbẹ ẹlẹran ọsin naa yoo janfani biliọnu kan yii.

O ni owooya ni wọn yoo fi owo naa se fun awọn agbọ lati gbe isẹ wọn soke ki eto ọrọ aje lee burẹkẹ sii.

"Kii se fun awọn agbẹ ẹlẹran ọsin aladanla nikan o sugbọn lati se igbọnwọ fun awọn darndarn to n da họwuhọwu silẹ ati wahala to n waye gbogbo."

Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán Awọn aarẹ ati adajọ agba to ti figbakanri jẹ pẹlu awọn gomina ipinlẹ ni wọn wa ninu igbimọ majẹobajẹ to ga julọ lorilẹede Naijiria

Bakannaa ni Igbimọ majẹobajẹ to ga julọ lorilẹede Naijiria tun buwọlu iyansipo awọn eeyan kan ni ajọ isedajọ (NJC), ajọ eleto abo (INEC) ati ajọ ikaniyan (NPC).

Lara awọn olori orilẹede Naijiria tẹlẹ to wa nibi ipade naa ni Ọgagunfẹyinti Yakubu Gowon ati Abdusalaam Abubakar pẹlu Oloye Olusẹgun Ọbasanjọ.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: