Fayose, Lai Mohammed sọrọ lori ikọlu ileewe Dapchi

Awọn akẹkọ ileewe girama ẹkọsẹ ọwọ fawọn obinrin to wa ni ilu Dapchi, ni ipinlẹ Yobe

Oríṣun àwòrán, YOBE STATE GOVERNMENT

Àkọlé àwòrán,

Iye awọn akẹkọ to sọnu ko tii di mimọ bayii

Gomina Ayọdele Fayose ti ke si ijọba apapọ orilẹede Naijiria lati dẹkun 'irọ ti o n pa lori ọrọ gbigbogun ti idukulaja ikọ Boko Haram.

Gomina Fayose ti o jẹ ọkan pataki lara ẹgbẹ oselu PDP, iyẹn ẹgbẹ oselu alatako lorilẹede Naijiria ni kii se ohun to pamọ mọ bayii wipe ni gbogbo igba ti ijọba apapọ ba ti fọnrere wipe awọn ti sẹgun ikọ apanijaye yii ni ikọ naa tun maa n gba ọna ẹburu yọ pẹlu ikọlu to lagbara lorilẹede Naijiria.

Ọgbẹni Ayọdele Fayose ni o yẹ ki ijọba apapọ tete wa wọrọkọ fi ṣ'ada lori sise awari awọn akẹkọ ileewe girama ẹkọsẹ ọwọ fawọn obinrin to wa ni ilu Dapchi, ni ipinlẹ Yobe.

Amọsa, minisita fun eto iroyin lorilẹede Naijiria, Alhaji Lai Mohammed ti salaye wipe isẹlẹ to sẹlẹ ni ipinlẹ Yobe ko fihan wipe ijọba ko se isẹ rẹ bi isẹ lori ọrọ naa tabi boya ipolongo rẹ wipe oun ti sẹgun gulegule awọn ikọ Boko Haram lorilẹede Naijiria.

Àkọlé àwòrán,

Lai Mohammed ni ọsẹ ikọ Boko Haram ko sda bii ti igba ti ijọba yii ko si lori oye

Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, Alhaji Lai Mohammed ni ọsẹ ikọ Boko Haram ko sda bii ti igba ti ijọba yii ko si lori oye.

"Ni ọdun 2015, Boko Haram gbalẹ o gbode ni tobẹẹ gẹ to jẹ wi pe ninu ijọba ibilẹ mẹtadinlọgbọn to wa ni ipin lẹ Borno, ogun ninu rẹ lo wa ninu ikawọ awọn ikọ Boko Haram.

"Nigba naa ko si ibi ti wọn ko ti se ibajẹ; ọfiisi ọga ọlọpa orilẹede Naijiria, wọn lọ sibẹ, wọn ju ado oloro sibẹ, ile iwe iroyin ThisDay, ibudokọ Yanyan, ẹẹmeji ni wọn ju adooloro sibẹ.

"Nigba wo lẹ gbọ ti iru eyi sẹlẹ lati igba ti ijọba yii ti de ibẹ. Gbogbo ẹni to ba mọ nipa iogun igbesunmọmi yoo kan sara si ijọba yii."

Lọjọ aje ni awọn agbebọn kọlu ileewe girama ẹkọsẹ ọwọ fawọn obinrin to wa ni ilu Dapchi, ni ipinlẹ Yobe lati igbanaa wa ni iroyin lorisirisi ti n jade lori awọn akẹkọ ileewe naa ti o di awati lẹyin isẹlẹ naa.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: