Tinubu kọ lẹta si Odigie pe o'n gbegi di'na iṣẹ oun

Adari agba fun ẹgbẹ oṣelu naa lorilẹẹde Naijiria, Aṣiwaju Bọla Tinubu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọpọ ipinlẹ lo n koju aawọ abẹnu ninu ẹgbẹ APC lorilẹede Naijiria

Aawọ abẹnu ti o'n ba ẹgbẹ oṣelu APC finra tun ti gbo'na mi yo pẹlu bi adari agba fun ẹgbẹ oṣelu naa lorilẹẹde Naijiria, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ṣe kowe si Alaga ẹgbẹ, John Odigie Oyegun.

Ninu iwe naa ẹyi to fi ṣọwọ si Aare Buhari, igbakeji Aarẹ Yemi Osinbajo, Aarẹ ile asofin agba, Bukola Saraki ati abẹnugan ile aṣofin, Yakubu Dogara, Tinubu ni o kan oun lomi nu bi alaga Odigie Oyegun ti ṣe'n ṣe adina gbooku iṣẹ ti Aarẹ Buhari gbe fun oun.

Ninu iwe naa to fi ṣọwọ si awọn oniroyin, Tinubu ni 'Niṣe ni ijakulẹ ọkan bami nigba ti mo ri wi pe o gbe igbesẹ to tako ọrọ ajọsọ wa.' 'Kaka ki o kin mi lẹyin lori sisọ ẹgbẹ wa ji pada, ni ṣe ni o duro gẹgẹ bi adina si erongba wa.'

A gbiyanju lati ba agbẹnusọ ẹgbẹ APC Bolaji Abdullahi s'ọrọ nipa iṣẹlẹ yi ṣugbọn ko gbe ipe rẹ.

Aawo Tinubu ati Odigie ko ṣẹṣẹ bẹrẹ

Awọn amoye sọ wi pe o ti pẹ ti awọn mejeeji ko tii gbọrawọn ye lori didari ọrọ ẹgbẹ APC.

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Àkọlé àwòrán,

Awọn amoye sọ wi pe o ti pẹ ti awọn mejeeji ko tii gbọrawọn ye lori didari ọrọ ẹgbẹ APC

Ṣaaju akoko yi, awọn mejeeji ti woju ara wọn nigba ti igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ APC ti Odigie dari rẹ ko lati kin ayanfẹ Tinubu, James Faleke, lẹyin lati tẹsiwaju gẹgẹ bi oludije ninu idibo Gomina nipinlẹ Kogi.

Ni ipinlẹ Ondo ọrọ dojuru si nibi ti igbimọ amuṣẹya ti fi ountẹ lu idibo alabẹle to yan Rotimi Akeredolu gẹgẹ bi ẹni ti yoo gbe apoti idibo labẹ asia ẹgbẹ fun ipo Gomina nipinlẹ naa.

Wọn gba Segun Abraham ti Tinubu kin lẹyin sẹgbẹ kan.

Ara o r'okun ara o r'adiyẹ

Kayode Eesuola ti o jẹ olukoni agba ni ẹka imọ eto ijinlẹ oṣeelu ile eko fasiti Eko ni bi wọn ṣe bẹrẹ APC ko le jẹ ki ọrọ wọn toro.

O ṣalaye wi pe aburu ti eleyi le fa ni wipe anfaani to yẹ ji ara ilu jẹ lọdọ ẹgbẹ to wa ni ijọba yoo di oun igbagbe.

Ẹ gbọ ohun ti o wi siwaju sii ninu fọran yii:

Àkọlé fídíò,

Ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Kayode Esuola

Ọpọ aawọ le ṣe okunfa ipinya APC

Comrade Kola Ibrahim to jẹ awoye ọrọ oṣelu ni bayi ti ibo 2019 ti'n sunmọ oriṣiriṣi ni yoo ma ṣele ni gbagede oṣelu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Aare Buhari n fẹ ojutu si aawọ abẹle ninu APC

O ṣalaye pe 'ẹni ti yoo ba pari aawọ gẹgẹ bi iṣẹ ti wọn gbe fun Tinubu, oun gaan ko gbọdọ maa ni ija pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ.

O tepelemọ bi o ti ṣe ṣe pataki lati yanju aawọ yi ti wọn ba fẹ ki ẹgbẹ naa mu itẹsiwaju ba ara ilu.'

Diẹ ninu awọn ipinlẹ ti omi ẹgbẹ oṣelu APC ko ti toro ree:

  • Oyo: Gomina Abiọla Ajimọbi ati Minisita feto ibaraẹnisọrọ, Adebayọ Shittu ngbena woju ara wọn
  • Kaduna: El Rufai ati Sẹnatọ Shehu Sanni nwọ Sokoto kanaa eyi to n fa laasigbo lọwọ
  • Gombe: Gomina Danjuma Goje ati Sẹnatọ Usman Nafada kii foju rinju
  • Ogun: Gomina Ibikunle Amosun ati Sẹnatọ Ọlamilekan Adeọla dijọ nṣe fanfa
  • Plateau: Gomina Simon Lalong ati minisita fọrọ ere idaraya, Solomọn Dalung nṣe bii ata ati oju.

Aawọ to n waye lopo ipinlẹ ti ẹgbẹ APC ti'n ṣe ijọba lo mu ki Aarẹ Muhammadu Buhari kede ifilọlẹ igbimọ kan ti Asiwaju Bọla Tinubu ko sodi lati doola aawọ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC jakejado Naijiria.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: