Obin n sukun, ijọba ko mọ ibi tawọn akẹkọbirin Dapchi wa

Aworan ojuta ile iwe Dapchi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ikọlu to ba ile-iwe girama to wa ni abule Dapchi nipinlẹ Yobe ti fẹ fi ara jọ bi awọn ikọ Boko Haram ti kọlu ileewe girama Chibok ti wọn si ji awọn akẹkọbirin ọdurun din ni mẹrinlelogun lọ ni ọdun 2014.

Ni bayii awọn obi awọn ọmọ bi ọgọrun ti wọn sọnu ni ile-iwe abule Dapchi ti n sunkun nigba ti awọn alaṣe n sọ awọn ọrọ ti wọn tako arawọn nipa ipọ ti awọn akẹkọbirin naa wa.

Lẹyin igba ti wọn ji awọn akẹkọbirin Chibok gbe, ijọba dakẹ lai sọ nkankan. Ṣugbọn ileeṣẹ ologun Naijiria kede wipe oun ti gba awọn ọmọ ile-iwe naa la. Lẹyin naa ni ileeṣẹ na ba sọ wipe ọrọ naa ko ri bẹ mọ.

L'akọkọ ijọba Naijiria ti ọdun 2014 ko mọ bi ọrọ naa ti tobi to saaju ki wọn o to ma polongo BringBackOurGirls.

L'asiko yi gan ọrọ naa kun fun iruju nibi ti awọn alaṣẹ ti kọkọ daba wipe awọn ti gba awọn ọmọ naa silẹ ki wọn o to wa tọrọ aforijin lẹyin ọrẹyin wipe ọrọ na ko ri bẹ.

Titi di isin yii wọn ko ti fi idi ọrọ mulẹ nipa ibi ti awọn akẹkọbirin naa wa ati ounka wọn.

Awọn kan n sọ wipe awọn akẹkọbirin naa to adọta nigba ti awọn kan si wipe awọn ọmọ ile iwe naa to ọgorun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Har yanzu akwai ragowar 'yan matan Chibok kusan 100 da ba a gano ba

Ko si ti si ẹri kan to muna doko to le fi han wipe awọn ikọ Boko Haram ni wọn gbe awọn ọmọ ile iwe naa lọ.

Ṣugbọn nkan ti ko ni tabi-tabi ni ibanujẹ ọkan ati ainidaniloju awọn obi awọn akẹkọbirin naa.

Obirin kan to jẹ ọkan lara awọn obi awọn ọmọ naa sọ wipe "Ti mọ ba ranti wipe ki se l'ọrun lo wa ati wipe n ko mo iru ipo to wa, ti mo ba ronu bi wọn ti maa s'afihan aworan awọn ti wọn ji gbe, ma kan maa sukun ni lai dakẹ. Ki wọn gbe oku rẹ wa ki wọn si gbe sin o ya ju kin ma le ri lọ."

Ọkan lara awọn obi awọn ọmọ naa, Adamu Muhammed, sọ wipe "Lotitọ ti wọn ba se iru nkan bai si yan inu rẹ ko ni dun, sugbọ gẹgẹ bi Musulumi, gbogbo nkan to ba sẹlẹ si mi, maa kan ti si Ọlọrun mi ni.

"Ṣugbọn nkan ti wọn se fun wa ko dara rara. Ọmọ ọdun mẹdogun l'ọmọ mi. Ipele kinni lowa ni ile-ẹkọ girama agba (SS1). Ẹmi ko mọ ibi ti ọmọ mi wa. Awa (ti ako mọ ibi awọn ọmọ wa wa) pọ gidigan.

"O damiloju wipe ijọba Buhari ni wọn fẹ fi ijinigbe yii koba. Bi kii ba se bẹ, eleyi jẹ nkan to n runi loju ni."

Lootọ awọn obi awọn ọmọ Dapchi wọn ko ni sọ ireti nu sugbọn awọn kan lara awọn obi awọn akẹkọbirin Chibok sin reti awọn ọmọ wọn lẹyin ọdun mẹrin ti wọn ti ji wọn gbe.

Nkan ti awọn onwoye n wi ni pe ọwọ yẹpẹrẹ ti wọn fi mu ọrọ ibi ti awọn akẹkọ naa wa lo fa ti ko fi ti ni ojutu bayii.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: