Yobe: Ọlọpa n wa obi ọmọ ti Boko Haram ji gbe ni Dapchi

Aworan awọn ologun ati awọn asoju ijọba ti wọn de bi ti isẹlẹ na ti waye Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Minisita feto iroyin ati asa ni Naijiria, Lai Mohammed sọ wipe ijọba n gbiyanju lati ri wipe awọn ọmọ naa pada wa

Ọkan lara awọn obi tawọn ọmọ wọn sọnu l'abule Dapchi nipinlẹ Yobe ti sọ fun BBC wipe oun ti farapamọ lẹyin igba ti ọlọpa kede pe ki wọn mu oun.

O sọ wipe awọn ọlọpa se kede naa lẹyin igba tawọn obi naa lẹ oko mọ awọn ọkọ ti

gomina Ibrahim Geidam ngbe lọ si Dpachi lati lọ sọ fun wọn wipe wọn ko tii ri awọn ọmọ wọn.

Awọn akẹkọbirin naa wa ninu ile iwe girama Dapchi ni, nigba tikọ Boko Haram ya bo abule naa ti wọn si tun kọlu ile iwe girama naa pẹlu.

Sugbọn ileesẹ ọlọpa ko ti fesi lati fidi rẹ mulẹ boya lootọ ni wọn pasẹ pe ki wọn lọ mu obi akẹkọbirin naa abi bẹẹkọ.

Awọn obi awọn akẹkọbirin ti wọn to ọgorun si nreti iroyin nipa ibi tawọn ọmọbirin wọn wa.

Ọkunrin naa ti ko fẹ f'orukọ rẹ silẹ sọ wipe oun ni lati sa wọ inu igbo lọ, lẹyin igba ti oun gbo nipa ase ti wọn pa lati mu un.

Ọmọ re obinrin ti sọnu lati ọjọ aje nigba ti ikọ Boko Haram kọlu abule wọn ti wọn si yabo ile iwe girama awọn ọmọbirin to wa nilu naa.

Awọn alase kuna lati gba pe wọn ti ji awọn akẹkọbirin naa titi di alẹ Ọjọru amọ ti wọn kede wipe wọn ti gba awọn ọmọ kan la.

Nigba to nba awọn obi awọn ọmọ naa sọrọ l'Ọjọbọ, gomina ipinlẹ Yobe tako ikede naa eyi to mu kawọn obi fi ibinu sọ awọn ọkọ rẹ l'oko.

Baba akẹkọbirin naa sọ wipe, oun gbọ wipe wọn fe mu oun ni nitori ikọlu naa, sugbọn oun lero wipe wọn fe mu oun ni nitori ki oun ma baa bawọn ileesẹ iroyin s'ọrọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn obi ti wọn ji ọmọ wọn gbe si n reti iroyin nipa ibi t'awọn ọmọ wọ̀n wa

Irufẹ awọn iroyin to n tako ara wọn yii jọ nkan to sẹle lẹyin igba ti wọn ji awọn akẹkọbirin Chibok gbe l'ọdun 2014.

Ọgorun ninu awọn akẹkọbirin Chibok naa ni wọn ko ti pada wale di isin yii.

Nigba to n ba ileesẹ BBC sọrọ, minisita feto iroyin ati asa ni Naijiria, Lai Mohammed, sọ wipe ijọba n gbiyanju lati ri wipe awọn ọmọ naa di riri pada.

Ọ fi kun wipe ijọba ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ naa gẹgẹ bawọn eeyan kan ti nsọ.