Naijiria: Asiri awọn ibudo igbafẹ ẹranko

ìnàki Image copyright CHESTER ZOO
Àkọlé àwòrán Inu igbó kìjikìji lawọn ìnàki orilẹede Naijiria n gbe

Awọn inaki ti wọn jẹ ti orilẹede Naijiria ati ilẹ Cameroon ti wọn ti ri ni awọn igbo Gashaka Gumti, ti eyi si jẹ́ ireti pe awọn inaki ọhun ni ọjọ́ ọla.

Awọn oludaabobo awọn ẹranko ti se awari akìka to tobi ju fun igba akọkọ lorilẹede Naijiria.

Igbo ẹran Gashaka Gumti wa lara awọn ohun amusagbara orilẹede yii sugbọn ti ọkan lara awọn isoro to n koju ni kiko awọn eranko inu rẹ lọ si awọn agbegbe miiran.

Awọn oluwadi se ayewo ibudo igbafẹ ẹranko naa, ti wọn si sakiyesi pe yatọ sawọn akojọpọ eweko,òkè ati pẹ̀tẹ̀lẹ̀ tun wa ninu igbo ọhun.

Igbo yii lo jẹ̀ ilegbe fun ọ̀pọ̀ awọn ẹranko ti wọn wa ninu ewu jù lẹkun ìwọ̀ oorun Afrika.

Image copyright CHESTER ZOO
Àkọlé àwòrán Igbo Gashaka Gumti wà lara awọn diẹ to sẹku ninu awọn igbo ẹranko lorilẹede Naijiria

Erọ ayaworan ọhun ri ọ̀pọ̀ awọn ẹranko méríìrí lagbegbe yii, bii ìnàkí.

Stuart Nixon to jẹ́ alamojuto ibudo igbafẹ ẹranko sọ pe, sise awari agbegbe tawọn ìnàki yii wa jẹ́ aseyọrí ti ko lẹ́gbẹ́.

O ni, "Fun ọ̀pọ̀ ọdun ni wọ̀n ti ri Gashaka gẹ̀gẹ̀ bi igbo to ni awọn ìnàki to pọ̀ jùlọ lorilẹede Naijiria ati Cameroon, eleyi to sọ̀wọ́n jọjọ."

"A ri inaki gẹ̀gẹ̀ bii ara ẹranko to se pataki jù, ìdí niyi ta fi nílò lati kà wọn, ka si ri ipò tawọn ìnàkí ọhun wa lọ́wọ́lọ́wọ́, eyi yoo se afihan iyatọ̀ to wa laarin ohun taa mọ̀ nipa awọn inaki yii tẹ́lẹ̀ rí".

Awọn aginjù ti wọ́n ti gbàgbé

Awọn inaki wa ninu ewu lorilẹ̀ede Naijiria ati Cameroon. Awọn inaki naa ti dinku si ẹgbẹrun mẹsan, to si jẹ pe inaki to to ẹgbẹrun kan nireti wa pe wọn n gbe ni ibudo igbafẹ ẹranko lorilẹede yii.

Awọn ẹya ọ̀bọ n kojú orisirisi isoro, bii pipaje, fifi wọn se oogun abẹnu gọngọ ati sisọ̀ ilégbèé wọn nù.

Awọn onimọ nipa ẹranko igbẹ ti n se iwadii ninu igbo ọhun lori iye awọn ẹranko to n gbe ibẹ̀ ni pàtó, nitori ko si iwadii lori iye awọn ẹranko ọhun lati bi ogun ọdún.

Image copyright CHESTER ZOO
Àkọlé àwòrán Awọn akika n koju isoro kíkó kuro ni ibùgbé wọn

Erọ ayaworan ọhun ká ẹranko to le ni ẹgbẹrun lọna aadọta laarin ọdun 2015 ati 2017.

Nixon sọ pe, "Erọ ayaworan jẹ irin isẹ ti kò lẹgbẹ lati sáfihan igbo ti wọn ti gbagbe lorilẹede Naijiria gẹgẹ bii ilégbèé fun awọn ẹ̀yà ẹranko to se pataki lorilẹede Naijiria ati ilẹ Afrika ni pataki julọ."

Awọn oníwàádìí ọhun ni, o jẹ iyalẹnu fun awọn pe akika to jẹ ẹranko ti ko wọ́pọ̀, ti ọ̀pọ̀ eniyan si maa n wa kaakiri nitori ìpẹ́ to ni lati fi se oogun ibil,ẹ lawọn tun sàwárí ninu igbo ọhun.

Image copyright CHESTER ZOO
Àkọlé àwòrán Awọn Àmọ̀tẹ́kùn kii saaba fara wọn hàn
Image copyright CHESTER ZOO
Àkọlé àwòrán Awọn ológbò alawọ̀ wúrà nilẹ̀ Afrika n gbe ninu agunju equatorial nilẹ̀ Afrika

Wọn tun sawari ológbò alawọ̀ wúrà nilẹ̀ Afrika ninu awọn àwòrán ọun.

Nixon tun sọ pe "O seé se ko jẹ pe orilẹede Naijiria ni ẹya ológbò alawọ̀ wúrà ilẹ̀ Afrika ọhun to pọ̀ jùlọ kù sí, ati pe, o jẹ ohun tawọn oniwadii ko mọ pupọ̀ nipa rẹ̀."

Ibudo ọgba ẹranko Chester ti n se iranlọwọ fun igbo ẹran Gashaka Gumti, ti wọn si n gbiyanju lati ri pe, aabo to péye wà fawọn ẹranko to wa ninu igbo ọhun.

Yohanna Saidu to jẹ́ osisẹ́ ileesẹ́ to n rì sí ọ̀rọ̀ awọn igbó ẹran ati olusó agba nigbo ẹran Gashaka Gumti sọ pe ibi ta le fi safiwe ẹwà igbo ẹran ọhun nilẹ̀ Afrika ko to nnkan.