Buhari: Ẹ fun mi laaye diẹ si lori ipinnu ibo 2019

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Awọn eekan ilu kan ni Naijiria nsin Buhari ni gbẹrẹ ipakọ lati mase dibo lẹẹkeji

Olori orilẹede Naijiria, Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ fawọn gomina ipinlẹ labẹ ẹgbẹ oselu APC pe ki wọn fun oun ni aaye diẹ si lati pinnu lori boya oun yoo tun gbegba ibo aarẹ lẹẹkeji.

Aarẹ Buhari kede ọrọ yi fawọn gomina ẹgbẹ APC lasiko ipade to se pẹlu wọn nile ijọba nilu Abuja.

Gomina Rochas Okorocha, tii se alaga fawọn gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu APC lo kede ọrọ yi fawọn akọroyin lẹyin ipade bonkẹlẹ ti aarẹ Buhari bawọn se.

Okorocha ni Buhari seleri pe oun yoo bawọn ọmọ ẹgbẹ APC atawọn ọmọ Naijiria lapapọ sọrọ lori ipinnu rẹ.

Awọn gomina lọ sepade lẹẹmeji ninu ọsẹ kan pẹlu Buhari

"Ifẹ awọn gomina ni pe ki aarẹ Buhari dije pada gẹgẹbii aarẹ orilẹede yi nitori bo se ti saseyọri lati ọdun meji sẹyin.O si da wa loju pe to ba tun tẹsiwaju, orilẹede Naijiria yoo tubọ dara si ni.

Bi o tilẹ jẹ pe ero ọpọ eeyan ni pe ọrọ oselu ni ipade tawọn gomina naa se pẹlu Buhari ni ẹẹmeji laarin ọsẹ kan da le lori, amọ Okorocha ni awọn s'abẹwo sọdọ Buhari lati baa kẹdun lori iku meji lara mọlẹbi rẹ to jalaisi laipẹ yii.