Afrika: Awọn aworan awodamiẹnu lọsẹ yi

Akojọpọ awọn aworan to jẹ agbayanu nilẹ Afrika ati tawọn ọmọ adulawọ lọsẹ yii.

Ajo to n daabo bo ẹranko igbo lorilẹede Kenya fun erin kan labẹrẹ eyi yoo mu ki wọn lee si nipo pada nigba ti won n ko awon erin kuro lagbeegbe Solio, Sangare ati Lewa lọsi ile itọju awọn ẹranko ni Tsavo East n Ithumba. Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ojojumọ kọ la ma n ri erin to n fo loke-sugbọn bọrọ ọhun se ri niyi lọjọru lagbeegbe Nyeri,lorilẹede Kenya.
Awọn osere Canada Carpe Diem Circus n sere ni Circus Festival - 15 02 2018. Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Eyi ni awọn eniyan to n fo nilu Abidjan, Ivory Coast lasiko ti wọn se ere idaraya akọkọ ti Circus Festival.
Aworan awọn to n sedaro nilu asaaju ẹgbẹ oselu alatako naa nlui Humanikwa lagbegbe Buhera. Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ni orilẹede Zimbabwe, awọn eniyan pejọ lati sedaro asaaju ẹgbẹ oselu Movement for Democratic Change (MDC), Morgan Tsvangirai to ku lọmọ ọdun marundinlaadọrin.
Aworan ọmọ tuntun jojolo, nile iwosan to ni yara agbebi marun pere nitori ogun abẹle to n ba orilẹede South Sudan fira. Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Lọjọ kan naa, iya kan n bimọ tuntun jojolo ni olu-ilu South-Sudan, Juba. Nibi tajọ Unicef ti ni o jẹ ọkan lara awọn agbegbe to lẹwu lati bimọ si lasiko yii.
Obinrin ajagun fẹyinti meji n se iwọde lasiko iranti awọn to ku nibi isẹlẹ isekupani 'Addis Ababa Massacre' Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ni Ethiopia, awọn ajagunfẹyinti se iwọde iranti isekupani to waye nilu Addis Ababa (Addis Ababa Massacre) nibi tawọn eniyan to le lẹgbẹrun lọna ogun ti padanu ẹmi wọn sọwọ awọn ọmọogun orilẹede Italy, lọdun 1937.
Awọn eeyan orilẹede Libya mu asia orilẹede wọn lọwọ niranti Muammar Gaddafi ni paapa isere to wa ni Tripoli - 17 02 2018. Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Awon eeyan orilẹede Libya naa ko gbẹyin ninu sise iranti ọjọ pataki kan, Ọjọ kẹtadinlogun osu keji ni iranti ọdun keje ti wọn yẹ aga mọ Ọgagun Muammar Gaddafi nidi
Aworan ipolongo aarẹ Egypt ni Cairo - 21 02 2018. Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Lẹyin odi, orilẹede Egypt n se igbaradi fun idibo,bẹẹ ni awọn olupolongo n lẹ aworan aarẹ orilẹede naa kaakiri
Aworan bii aarẹ orilẹede South Africa se de lati sọrọ lori ọrọ n lọ lorilẹede naa nile igbimọ asofin lọjọ kẹrindinlogun,osu yii. Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Orilẹede South-Africa ko tii se idibo, sugbọn o ti ni aarẹ tuntun. Cyril Ramophosa niyi nibi to ti nsọrọ lori 'Ọrọ n lo lorilẹede naa'. Afe mọ ohun ti obinrin yii n wo.
Aworan Akwasi Frimpong nibi to ti n ba ọmọ rẹ sere - 16 02 2018 Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Lapa ibomiran lagbaye, lorilẹede South Korea, ọmọ bibi ilu Ghana to n kopa ninu ere idaraya fifi ayawọ, Akwasi Frimpong , n fi ọrẹ tuntun han ọmọ rẹ.
Aworan awọn ọkunrin to n se igbaradi fun idije naa ni Kenya - 17 02 2018. Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Amọ lorilẹede Kenya, ero ọkan awọn elere idaraya ni igbaradi fun idije ere idaraya Commonwealth ti yoo waye lorilẹede Australia losu Kẹrin.

Aworan wọnyii wa lati ileesẹ AFP ati EPA