Ẹgbọn-taburo ṣegbeyawo nipinlẹ Anambra

Ọwọ ọkọ ati iyawo kan pẹlu oruka igbeyawo lọwọ wọn Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn araalu Agba ni eewọ ni igbeywao naa

Awọn ara abule kan nipinlẹ Anambra lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, dana sun ile ijọsin awọn ọmọlẹyin kristi kan lẹyin ti alufa ijọ naa so ọkunrin kan ati aburo rẹ obinrin pọ gẹgẹ bi ọkọ ati aya.

Awọn araalu Agba, lagbegbe Ekwulobia tọka si igbesẹ tẹgbọntaburo naa gẹgẹ bii eewọ.

Ọna lati fẹhonu wọn han si isin igbeyawo kayeefi ọhun, lo mu kawọn ọdọ ilu Agba, to ri igbeyawo naa gẹgẹ bi eewọ dana sun ile ijọsin ti isin igbeyawo naa ti waye.

Iroyin naa fidi rẹ mulẹ wipe ẹni to jẹ ẹgbọn ọkunrin fun awọn mejeeji lo dari eto isin igbeyawo naa, to si tọka si awọn ẹsẹ Bibeli kan lati fi gbe igbeṣẹ rẹ ọhun lẹsẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iya awọn ọmọ naa fi ọwọ si igbeyawo wọn

Ohun to tun jẹ kayeefi ninu iṣẹlẹ naa ni wipe, niṣe ni iya awọn ọmọ naa sọ fawọn akọroyin pe igbesẹ awọn ọmọ ohun ba Bibeli mu, pẹlu afikun wipe: "ọmọ mi san owo ori boṣetọ ati boṣeyẹ."

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Iroyin lati ori ẹrọ ayelujara ni ọmọkunrin naa, to jẹ ẹni ọdun marundinlọgbọn ti fun aburo rẹ naa l'oyun.