Oyegun lọ ri Buhari nitori lẹta Tinubu

Aworan Buhari ati Tunubu Image copyright Nigerian Government

Alaga ẹgbẹ oselu APC, John Odigie-Oyegun ti sare lọ ri Aarẹ Buhari lẹyin ti Bola Tinubu wipe Oyegun n gbegidina isẹ iparija ẹgbẹ naa.

Ileeesẹ Iroyin Naijiria (NAN) sọ wipe alaga ẹgbẹ naa, to se'pade pẹlu Aarẹ Naijiria lẹyin irun Jimọh l'ọjọ Ẹti, kọ lati sọrọ nipa ipade naa.

Sugbọn ileesẹ iroyin naa sọ wipe oun gbo pe aarẹ ati alaga ẹgbẹ na jiroro lori lẹta ti Tinubu kọ wipe Oyegun n s'atako fun igbiyanju rẹ lati pari aawọ to wa laarin awọn ọmọ ẹgbẹ naa.

Buhari yan Tinubu lati lewaju ifọrọwerọ, iparija ati ifọkan balẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ naa saaju ibo ọdun 2019.

Ninu lẹta ifẹdun-ọkan-han eleyi to kọ si Odigie-Oyegun to si fi ranse si Aarẹ Buhari naa, Tinubu f'ẹsun kan alaga ẹgbẹ naa wipe o n gbegidina iyanju ati pari aawọ to wa ninu ẹgbẹ naa.

Image copyright Getty Images

Tinubu ti bẹrẹ isẹ Aarẹ Buhari gbe fun pẹlu sis'abẹwo si Sokoto ni iwọ-oorun ariwa Naijiria.