Fayose: Emi ko ni bẹ Buhari

Aworan gomina ayọdele Fayose

Oríṣun àwòrán, @GovAyoFayose

Àkọlé àwòrán,

Fayose wa lara awọn to lewaju atakọ si ijọba Muhammadu Buhari ati ẹgbẹ oselu APC to n se ijọba lọwọ bayii lorilẹede Naijiria

Gomina ipinlẹ Ekiti lorilẹede Naijiria, Ọgbẹni Ayọdele Fayọse ti ke gbajare sita wipe irọ lasan ni ọrọ ti awọn eeyan kan n kọ kiri wipe oun ti tuba lori gbogbo ọrọ ti oun sọ nipa aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ati isejọba rẹ.

Fayọse ni ko si ohun to fara pẹ iroyin naa ati pe digbi bayii lohun duro ti gbogbo ọrọ ti ohun ti sọ nipa isejọba to wa lode bayii lorilẹede Naijiria.

Ni ọjọ Ẹti ni iroyin kaakiri wipe ẹnu ti igbin Fayose fi bu orisa Buhari, o ti fi ẹnu naa gbolẹ pẹlu ẹbẹ fun idariji.

Àkọlé fídíò,

Fayose sọrọ lori lẹta oloye Ọbasanjọ.

Amọsa nigba ti Fayose n sọrọ lori ikanni ibanisọrọ ayelujara twitter rẹ, o ni: "Ẹ kọ 'pakọ si iroyin ti o n lọ kaakiri wipe mo sọ wi pe mo kabamọ gbogbo ohun ti mo sọ nipa Aarẹ Buhari. Emi ko sọ irufẹ ọrọ bẹẹ jade rara. Isẹ ọwọ awọn eeyan ti ara wọn kọ ootọ ni."

Gomina ayọdele Fayọse wa lara awọn to lewaju atakọ si ijọba Muhammadu Buhari ati ẹgbẹ oselu APC to n se ijọba lọwọ bayii lorilẹede Naijiria.