PDP tako Buhari lori awọn ọmọ Dapchi

aworan ileewe Dapchi ni ipinlẹ̀ Yobe Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọrọ isẹlẹ ikọlu ati awari awọn ọmọ ileewe Girama ẹkọsẹ ọwọ awọn obinrin nilu Dapchi ni ipinlẹ Yobe se ti di ti alatagba laarin igun ati ẹka gbogbo lorilẹede Naijiria

Ẹgbẹ oselu alatako lorilẹede Naijiria, Peoples Democratic Party, PDP ti salaye fun awọn ọmọ orilẹede naa wipe irọ ti ijọba to wa lode lorilẹede Naijiria n pa fun araalu lo n se akoba fun igbesẹ ati tete sawari awọn ọmọ naa.

Ninu atẹjade kan to fi sita, agbẹnusọ fun ẹgbẹ oselu PDP, ọgbẹni Kọla Ologbondiyan ni o yẹ ki awọn ọmọ orilẹede Naijiria so aarẹ Buhari mu lori bi isẹ se nfalẹ.

Ẹgbẹ oselu PDP ni kani ẹgbẹ oselu APC to n sejọba lorilẹede Naijiria ko ti sọ fun araalu ni wipe awọn ti kapa ikọ Boko Haram ni, olukuluku ni yoo ti mọ bii yoo se maa rin tifura-tifura.

Ẹgbe naa sọ wipe ijọba APC n paro nitori ibo ọdun 2019, o si s'afikun wipe: "amọsa ohun to kọni lominu ju ni iwa ika gbaa ti o hu lati gbe ireti araalu soke pe ko si giiri nigba to si jẹ wipe ewu nbẹ loko longẹ fawọn eeyan agbegbe naa."

Ẹgbẹ oselu alatako lorilẹede Naijiria tun koro oju si akitiyan ijọba apapọ orilẹede Naijiria labẹ isakoso ẹgbẹ oselu APC lati p'ohun mọ agogo lẹnu lori isẹlẹ ijinigbe naa eleyi to ni o fa bi ọkan-o-jọkan iroyin to tako arawọn se wa n fo kaakiri ti o si n tipasẹ bẹẹ se adinagbooku fun igbesẹ lati se awari awọn akẹkọ ti wọn ji gbe naa.

Awọn obi awọn akẹkọbirin Dapchi ti gbe orukọ awọn ọmọ ti sọnu nileiwe naa.

Awọn ọmọ naa ni:

1. Fatima Bashir

2. Aisha Kachalla

3. Zainab Abubakar

4. Falmata Wakil

5. Fatima Isa

6. Fatima Musa

7. Aisha Usman

8. Aisha Adamu

9. Fatima Isa

10. Hauwa A. Mohammed Idriss

11. Maryam Mohammed

12. Fatima Mohammed II

13. Hauwa Salisu

14. Hassana Gambo

15. Aisha Adamu

16. Adama Garba

17. Zara Grema

18. Maryam Daamkontoma

19. Zainab Bama

20. Fatsuma Abdullahi

21. Fatima Yahaya Tarbutu

22. Amina Yahaya Tarbutu

23. Amina Adamu

24. Hajara Ali

25. Fatima Abdullahi

26. Fatsuma Ali

27. Zara'U Mohammed

28. Salamatu Garba

29. Falmata Alh. Inuwa

30. Falmata Alh. Ali

31. Aisha B. Danjuma

32. Maryam Bashir

33. Maryam Aliyu Mabu

34. Fatima Modu Bamba

35. Aisha Modu Bamba

36. Hafsat Haruna

37. Rabi Alh. Nasiru

38. Hadiza Moh'D

39. Fatima Aji Hassan

40. Falmata Wakil

41. Aisha Wakil

42. Falmata A. Audu

43. Aisha Maina

44. Aisha Mohammed

45. Aisha Mamuda

46. Name missing on list

47.Zainab Usman

48. Hadiza Mohammed Taiduma

49. Maryam Ibrahim

50. Fatima M. Gira

51. Hafsat Ibrahim Gira

52. Maryam Ibrahim

53. Zara Tijjani

54. Amina Haruna

55. Fatima Adamu

56. Khadija Mai Sale

57. Khadija Ali

58. Habiba Musa Jakana

59 Fatima Bukar

60. Hajara Gidado

61. Maryam Basiru

62. Fatima Usman

63. Maryam Ibrahim

64. Leah Sherubu

65. Aisha Alh. Deri

66. Fatima Hassan Mustapha

67. Zainab Manu

68. Zara Tijjani

69. Zainab Bukar Abba

70. Hauwa Saidu Abubakar

71. Karima Inusa

72. Amina A. Abubakar

73. Yakura Sani

74. Rabi Yahaya Tela

75. Hajara Yahaya Tela

76. Marya Mustapha

77. Aisha Abdullahi

78. Maryam Adamu Mohammed

79. Bintu Usman

80. Fatsuma Mohammed

81. Salamatu Isiyaku

82. Hauwa Lawan

83. Aisha B. Danjuma

84. Aisha Moh'D Jakusko

85. Hauwa Bulama

86. Fatima Abubakar Jambo

87. Walida Adamu

88. Fanna Mohammed

89. Aisha M. Bukar

90. Maryam Usman

91. Aisha Abba Aji

92. Maryam Usman

93. Maimuna A. Hassan

94. Zara Musa

95. Maryam Mohammed Kaku

96. Khadija Suleiman

97. Habiba Nuhu Dan Inu

98. Fatima Isiyaku Aliyu

99. Sahura Jibir Mohammed

100. Khadija Grema Dabuwa

101. Zara Grema Dabuwa

102. Zara Mohammed Lawan

103. Fatima Mohammed

104. Fati Modu Aisami

105. Fatsuma Alli.