Jamb fẹ fi tipa gba owo pada lọwọ osisẹ to kowo jẹ — Oloyede

Awọn akẹkọ idanwo aṣewọle s'ile ẹkọ giga, JAMB

Oríṣun àwòrán, @JAMB

Àkọlé àwòrán,

Ajọ JAMB sun opin ọjọ iforukosilẹ idanwo s'iwaju

Ajọ Jamb to n se eto idanwo asewole ẹkọ giga sọ wipe awọn ileesẹ ijọba mẹfa ọtọtọ ni wọn ran lọwọ lati gba owo ti wọn furasi wipe awọn osisse rẹ ji pada.

Adari Jamb, professor Ishaq Oloyede, to sọ eleyi di mimọ, wipe oun ko ni le sọ iye ti awọn afurasi sisẹ ajọ naa ko jẹ nitori wipe iwadi si n lọ lọwọ.

Lenu ijomẹta yii ni osisie ajọ jamb kan sọ wipe ẹjo lo gbe miliọnu merindinlogoji naira min ninu owo ajọ naa to di awati lọwọ rẹ.

Lẹyin naa ni ajọ Jamb da arabirin Philomena Chiese durọ nibi ise ti o si fa le awọn agbofinro l'ọwọ.

Sugbọn ajọ naa tun tu asiri jibiti to to miliọnu mẹtalelọgorin l'awọn eka rẹ to wa ni ipinlẹ Kano, Gombe , Kogi, Plateau ati Edo.

Professor Oloyede se ileri fun awọn ọmọ Naijiria wipe ajọ naa yoo gba gbogbo owo ti awọn osise rẹ gbe pada s'apo ijoba.

Awọn ileese to n ran Jamb lọwọ nibi iyanju ati gba owo naa pada ni: ileese ọlọpa, ajọ EFCC to n gb'ogun t'iwa-ibajẹ, ileesẹ abo-araẹni-labolu (NSCDC), ileese ọtẹlẹmuyẹ (DSS), ileeseẹ ton s'eto ilosiwaju imọ-ẹrọ ibanisọrọ (NITDA) ati ileesẹ ton mojuto awọn ileesẹ ẹrọ-ibanisọrọ (communication commission).