Ipinlẹ Ọyọ yoo da papa ijẹko silẹ fawọn darandaran

Darandaran fulani kan wa pẹlu agbo ẹran rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Wahala darandaran fulani ati agbẹ oloko ti di gbẹmigbẹmi lorilẹede Naijiria

Igba akeji gomina ipinlẹ Ọyọ, Ọtunba Moses Alake-Adeyemo ti sọ wipe ijọba ipinlẹ naa ti setan lati da awọn papa ijẹko silẹ lati wojuutu si gulegule wahala laarin awọn darandaran Fulani ati agbẹ olohun ọgbin nibẹ.

Otunba Moses Alake-Adeyemo salaye ọrọ yii lasiko to fi n sọrọ lori eto ileesẹ redio kan ni ilu Ibadan.

Igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ naa ni ọga oun, iyẹn gomina ipinlẹ Ọyọ ti tẹkọleti lọ si orilẹede Denmark bayii lati lọ ree gba imọ kun imọ lori eto dida papa ijẹko silẹ ki o lee bu mu ninu omi ọgbọn ati iriri wọn nibẹ.

O s'afikun wipe eleyii yoo dẹkun ija laarin agbẹ oloko ati darandaran Fulani to n fojojumọ waye.

"Afẹnuko gbogbo awọn gomina ni, paapaajulọ ijọba apapọ, lati rii daju pe a wa egbo dẹkun si wahala awọn darandaran Fulani ati agbẹ oloko eyi to ti di gbẹmigbẹmi lojoojumọ bayii."

Ipinlẹ Ọyọ wa lara awọn ipinlẹ to n fara kaasa wahala yii paapaajulẹ lawọn agbegbe okeogun, Ọgbomọsọ ati Saki.