Oṣiṣẹ alaabo yinbọn pa oluwọde ni Congo

Awọn osisẹ alaabo yin afẹfẹ tajutaju ati ibọn laarin igboro

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn osisẹ alaabo yi awọn ileejọsin ka

Ni orilẹede olominira Congo, DR Congo, ko din ni eeyan meji ti awọn osisẹ alaabo ti yinbọn pa ti awọn miran si tun farapa yanayana nibi iwọde tawọn ijọ ọlọrun kan n lewaju rẹ se lorilẹede naa lati tako ijọba Aarẹ Joseph Kabila.

Ikọ ọmọogun apẹtusaawọ ti ajọ isọkan agbaye n se agbatẹru rẹ lorilẹede naa salaye wipe ni olu ilu orilẹede Congo, Kinshasa ati ẹkun ariwa orilẹede naa ni ilu Mbandaka ni wọn ti yinbọn pa awọn oluwọde naa.

Iroyin sọ wipe awọn eeyan mẹtadinlaadọta ni wọn farapa ti awọn osisẹ alaabo si tun ko awọn miran to le ni ọgọrun si atimọle kaakiri orilẹede ọhun.

Awọn ọmọlẹyin Kristi ti gbimọran lati jade wọde lẹyin eto isin wọn lọjọ aiku sugbọn n se ni awọn osisẹ alaabo yi awọn ileejọsin ka ti wọn si lo afẹfẹ tajutaju ati ibọn lati fi sekilọ 'ma dan an wo' fawọn to fẹ wọde.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn ijọ Ọlọrun lo n lewaju ni Congo DR lati tako ijọba Aarẹ Kabila

Ni ilu Kisangani, o han si BBC wipe awọn alufaa mẹta wa lara awọn eeyan mẹẹdogun ti wọn fi si ahamọ.

Aṣoju pataki fun ajọ isọkan agbaye lorilẹede olominira Congo, DPR Congo, Leila Zerrougui ke sawọn alasẹ lati se iwadi to ku oju osuwọn lori awọn isẹlẹ naa.

Ni ọdun mẹtadinlogun sẹyin ni Aarẹ Kabila gba ijọba lọwọ babarẹ. Lọdun 2016 si ni saa isejọba rẹ pari.

Titi di bi a se n sọrọ yii ijọba ati ẹgbẹ alatako lorilẹede naa ko tii lee fi ẹnuko lori akoko fun idibo nibẹ.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: