Gomina ipinlẹ Yobe di ẹbi iṣẹlẹ Dapchi ru ileeṣẹ ologun

Minisita feto iroyin lorilẹ̀ede Naijiri, Lai Muhammed ati minisita kan pẹlu ọga ologun kan n sọrọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ijọba ipinlẹ Yobe ati ileesẹ ọmọogun lorilẹede Naijiria n tako arawọn lori ohun to sokunfa isẹlẹ ilu Dapchi

Gomina ipinlẹ Yobe lẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria nibiti o le lọgọrun akẹkọ ti di awati lọsẹ to kọja lẹyin ikọlu awọn agbebọn ikọ Boko Haram ti di ẹbi ohun to sẹlẹ ru awọn ologun o.

Gomina Ibrahim Gaidam ni isẹlẹ to sẹ lọsẹ to kọja naa waye lẹyin ọsẹ kan ti awọn alasẹ ileesẹ ologun ko awọn ọmọogun kuro ni ilu Dapchi nibi ti ileewe naa wa, lai jẹ wi pe wọn fi to ohun leti.

Gomina Ibrahim Gaidam salaye ọrọ yii fun akẹgbẹ rẹ lati ipinlẹ Borno, iyẹn gomina Kashim Shettima lasiko to wa baa kẹdun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

ko din nirun a ti n si n wa bayi ni ileewe naa.

Ipinlẹ Borno ni awọn ikọ agbebọn Boko Haram yii kan naa ti sọsẹ ni ọdun 2014 ti wọn ko awọn akẹkọbinrin to le ni igba nileewe kan ni ilu Chibok.

Ọgbẹni Gaidam tun seranti irufẹ isẹlẹ yii kan naa to waye ni ileewe miran nipinlẹ naa lọdun 2014 nigbati awọn agbebọn naa du ọpọ akẹkọ ọkunrin lasiko ti wọn fi n sun ni yara wọn.

"Mo fẹ sọọ laifọtape wipe, ko si ẹyọ ologun kan soso bayii ni ilu Dapchi lasiko ti isẹlẹ yii sẹlẹ.

"Nkan bi ọsẹ kan si asiko ti isẹlẹ na sẹlẹ ni wọn ti ko awọn ologun kuro nilẹ, laarọ yii si ni wọn sẹsẹ sọ funmi wipe ileesẹ ọmọogun n sọ wipe awọn ko figba kankan ko ọmọogun kuro nilẹ.

"Irọ to jinna si ootọ leleyi. Baalẹ ilu Dapchi wa nijoko nibi.

"Ko si ologun kankan ni ilu Dapchi tabi Buniyadi nibi ti wọn ni awọn ko ọmọogun si ni iwọn ibusọ ọgbọn si ilu Dapchi."

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ijọba ti seleri ati sawari awọn akẹkọ naa

O ni ọjọ kan naa ti awọn alasẹ ologun ko awọn ọmọogun kuro nilẹ nilu Buniyadi nipinlẹ Yobe lawọn apanijaye yii sọsẹ.

Amọsa o, ileesẹ ọmọ lorilẹede Naijiria ti salaye ninu atẹjade kan wipe awọn ko ko ọmọogun kuro lagbegbe naa.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: