PDP ni ki Buhari dẹkun ẹkun alabosi lori ijinigbe Yobe

Patako atọnisọna ileewe Dapchi naa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

PDP ni idarudapọ iroyin ati aigbọraẹniye laarin ẹka isejọba gbogbo kun ara ohun to mu awari awọn akẹkọ falẹ

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP to n lewaju ẹgbẹ alatako lorilẹede Naijiria ti ke si ijọba labẹ isejọba APC lati dẹkun ẹkun alabosi to n sun lori iṣẹlẹ ijinigbe ti o waye nileewẹ girama kan ni ipinlẹ Yobe.

Ẹgbẹ oselu PDP ni dipo aroye ti ijọba to wa lorilẹede Naijiria n ṣe bayii, asiko to lati dahun oniruuru awọn ibeere to nranju mọọ yi isẹlẹ naa ka.

Ẹgbẹ oselu naa to se ijọba laarin ọdun 1999 si 2015 ni pẹlu ọrọ ti gomina ipinlẹ Yobe, Alhaji Ibrahim Geidam sọ lori isẹlẹ ijinigbe naa wipe kiko ti awọn alasẹ ileesẹ ọmọogun ko awọn ọmọogun kuro ni agbegbe naa lo silẹkun gbaragada silẹ fun awọn ikọ adukukulaja naa lati wọle se ọsẹ wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn aadọfa akẹkọ ni ijọba kede wipe wọn ko tii ri bayi

Bi o tilẹ jẹ wi pe ijsba orilẹede Naijiria ti kede wipe gbogbo ohun elo to yẹ pata ni wọn yoo da sita lati sawari awọn ọmọ naa, ẹgbẹ oselu PDP ni ejo ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari lọwọ ninu pẹlu awọn iroyin asini-lọna ti o n jade eleyi to n se adinagbooku fun eto ati sawari awọn ọmọ naa.

Awọn ibeere ti PDP n bi ijọba Buhari ati ẹgbẹ oelu APC

A pe ileesẹ aarẹ nija lati wẹ ara rẹ mọ lori awọn ọrọ to yi jiji ti awọn amokunsika Boko Haram ji awọn ọmọ naa gbe.

Tani ẹni to pasẹ ki awọn ologun kuro ni agbegbe naa ati pw kini idi rẹ?

Kini awọn ọna eto abo miran ti wọn fi lelẹ lẹyin ti wọn ko awọn ologun kuro nibẹlati maa da abo bo awọn eeyan to wa nibẹ?

Tani ẹni to n sakoso iwa ọtẹlẹmuyẹ fun awọn eto abo nibẹ ati pe igbesẹ wo ni wsn gbe lati so okun abo ko le daindain ni agbegbe naa?

Ẹgbẹ oselu PDP wa ke si awọn ileesẹ alaabo lorilẹede Naijiria lati dide ji giiri si ojuse wọnki awọn akẹkọ naa lee di riri.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: