Awọn aṣofin Naijiria bẹrẹ igbesẹ didẹkun owo ẹru igbalode

Ọwọ ti wọn so sẹkẹsẹkẹ mọ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Owo ẹru igbalode ti di gbajugbaja lorilẹede Naijiria

Awọn asofin agba lorilẹede Naijiria yoo gunlẹ si ipinlẹ Edo ni ọjọ aje lati jiroro lori iwa fifi eeyan ṣowo kotọ eleyi to ti gbajugbaja lorilẹede Naijiria.

O din diẹ ni ẹẹdẹgbẹrun awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti wọn n ta owo si oko ẹru gẹgẹbi abajade iwadi kan lati ọdọ ajọ Global Slavery Index lọdun 2016.

Eleyi si ni awọn asofin agba orilẹede Naijiria ni ko yẹ ko tẹsiwaju bi gbogbo igbesẹ ijọba ati awọn alẹnulọrọ gbogbo ba ṣe rẹgi.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹnu kun Libya fun owo ẹru igbalode

Lasiko ijiroro naa, awọn sẹnatọ yoo fikunlukun pẹlu awọn to ti lugbadi owo kotọ yii, ajọ majẹobajẹ, atawọn aṣoju ilẹ-okeere gbogbo lori ọna lati dẹkun iwa kotọ naa.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: