'Oriṣiriṣi ọkunrin ni mo ba sun lọna ati jẹ ni Russia'

Awọn eeyan n sọkalẹ lati inu baluu Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ipo kẹtalelogun ni orilẹede Naijiria wa ninu awọn orilẹede to owo ẹru igbalode wọpọ si julọ lagbaye

Ọkan lara awọn ọmọbinrin ti wọn ko lọ ṣowo kotọ loke okun ti wi tẹnu rẹ lori ohun oju ri loke okun.

Ọmọdebinrin ọhun ti wọn fi orukọ bo laṣiri ṣalaye ara rẹ nibi ijiroro lori fifi awọn eeyan sowo ẹru, ti awọn aṣofin agba orilẹede Naijiria ṣe ni ilu Benin, lẹkun aringbungbun gusu orilẹede Naijiria.

"Lọdun 2013 ni awọn kan wa ba mi pe ki n kalọ si orilẹede Russia.

Wọn ni oṣu mẹfa pere ni maa fi ṣe owo aṣẹwo. Iwe aṣẹ irina ọmọ ileewe ni mo gba.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Naijiria lo tun se ipo karun un laarin awọn orilẹede Afirika to n gba oju oku mẹditarenia lọ si ilẹ Yuroopu

Lẹyin o rẹyin, ọdun meji ni mo lo ni orilẹede Russia. Orisirisi ọkunrin ni mo ba sun lọna ati jẹ."

O tẹ siwaju wipe, 'A ti mulẹ ki a to kuro lorilẹede Naijiria. Bi mo si ti de moscow ni wọn ti gba iwe irinna mi lọwọ mi. Ọga mi obinrin lo san owo irina mi.

Ki n to kuro lorilẹede Naijiria ni wọn ti sọ fun mi pe ẹgbẹrun lọna aadọta dọla owo ilẹ Amẹrika ni mo gbọdọ san pada laarin ọdun kan.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Owo to to biliọnu mọkanlelogun Naira ni ajọ isọkan ilẹ Yuroopu, EU ti na lori gbigbogun ti iwa kiko awọn eeyan lọ silẹ okeere lọ sowo kotọ lorilẹede Naijiria

Nkan bii onibara mẹfa si meje ni a nni lojumọ. Ẹpẹ igba ni wọn maa n fi ọlọpa mu wa nitoripe ofin o faye gba isẹ aṣẹwo nibẹ."

Ninu ọrọ rẹ, Aarẹ ileegbimọ aṣofin agba, lorilẹede Naijiria. Sẹnatọ Bukọla Saraki nipo kẹtalelogun ni orilẹede Naijiria wa ninu awọn orilẹede to owo ẹru igbalode wọpọ si julọ lagbaye.

Sẹnatọ Saraki ni orilẹede Naijiria lo gbe ipo kini ninu awọn eeyan to n ngba ọna aitọ Agadez route fi ko awọn eeyan lọ soke okun.

Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Awọn ti wọn fẹ fi se owo koto maa n mulẹ ki wọn to kuro lorilẹede Naijiria

O ni orilẹede Naijiria lo tun se ipo karun un laarin awọn orilẹede Afirika to n gba oju oku mẹditarenia lọ si ilẹ Yuroopu.

"Ida ẹgbẹta ni iye awọn ọmọbinrin Naijiria to n gunlẹ si orilẹede Italy nikan.laarin ọdun mẹta. Nkan bii ẹgbẹrun mẹwa awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni iwadi si sọ wipe o ti padanu ẹmi wọn ninu irinajo ẹni-ori-yọ-o dile yii laarin osu marun pere ninu ọdun to kọja."

Asoju ajọ isọkan ilẹ Yuroopu, Eulorilẹede Naijiria, Ketil Karlsen ati igbakeji asoju ijọ̀ba ilẹẹ Gẹẹsi lorilẹede Naijiria, ti awọ̀n pẹ̀lu kopa nibi ijiroro naa asiko ati karamasiki gbigbogunti fifi awọn eeyan sowo ẹru niyi fun gbogbo awọn alẹnulọrọ.

Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Pupọ awọn ti wọn ko lọ ni wọn ta si oko ẹru igbalode

Asoju ajọ isọkan ilẹ Yuroopu, Eulorilẹede Naijiria, Ketil Karlsen ni tirẹ salaye siwaju sii wipe, Owo to to biliọnu mọkanlelogun Naira ni ajọ isọkan ilẹ Yuroopu, EU ti na lori gbigbogun ti iwa kiko awọn eeyan lọ silẹ okeere lọ sowo kotọ lorilẹede Naijiria.

Minisita fun ọrọ abẹle, Abdulrahaman Dambazau ni ọrọ naa ti di ti amukun ẹru rẹ wọ, o ni oke lẹ wo, ẹ o wo isalẹ.

Ọgagun Dambazau tọka rẹ wipe ohun gan an to n se okunfa bi awọn ọdọ wọnyii se n gba lati kuro ni ilẹ baba wọn lọ si irinajo si inu ẹru lo yẹ ki tolori tẹlẹmu o yẹ wo.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: