Naijiria ko ọmọogun ati ọkọ ogun ofurufu lati wa awọn ọmọ Dapchi

Bata awọn akẹkọ lẹyin ikọlu Boko Haram ni Dapchi

Oríṣun àwòrán, AFP/Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn akẹkọ sa asala fun ẹmi wọn ninu ikọlu Boko Haram ni Dapchi

Orilẹede Naijiria ti kede wipe oun ti ko awọn ọmọ-ogun ati awọn ọkọ ofurufu sita lati wa awọn ọmọ ile-iwe to le lọgọrun ti awọn onijagidijagan agbesunmọmi Boko Haram jigbe ni ọsẹ to koja.

Awọn ọmọbirin naa sọnu lẹyin ti awọn afurasi ikọ ẹgbẹ Boko Haram lọ si ile-iwe wọn ni Ilu Dapchi ni ipinlẹ Yobe lọjọ kọkandilogun oṣu keji ọdun 2018.

Aare Muhammadu Buhari sọ pe o jẹ "ajalu nla fun orilẹede Naijiria" ati fun awọn obi ati ẹbi awọn ọmọbirin naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Awon obi n beree omo won lowo ijoba

Ikọlu naa ti n mu irufẹ isẹlẹ bẹẹ to sẹlẹ si awọn ọmọbinrin akẹkọ to le ni igba ti awọn Boko Haram ji gbe ni ile-iwe kan ni ilu Chibok ni ọdun 2014 wa si iranti.

Ibinu ti n suyọ laarin awọn obi awọn ọmọde wọnyi pẹlu awọn iroyin ti o jade sita wipe awọn ọmọ-ogun kuro ni awọn agbegbe Dapchi ni oṣu to kọja.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Awon obi kan tii nwa omo won ninu awọn ibi ti won koruko si

Dapchi to wa ni iha ariwa ilu Chibok fi oju wina ikọlu Boko Haram ni ọjọ aje ọsẹ to kọja ti o mu ki awọn akẹkọ ati awọn olukọni ileewe girama naa sa lọ farasinko sinu igbo lagbegbe naa.

Awọn olugbe agbegbe ọhun ni ileesẹ ologun lorile-ede Naijiria ati awọn baluu ogun ko ipa takuntakun lati le awọn agbebọn naa jinna.

Awọn alaṣẹ ijọba ti kọkọ sọ wipe ko si ẹni to ji awọn ọmọ naa gbe, atipe se ni wọn sa lọ farapamọ kuro lọwọ awọn agbebọn naa.

Ṣugbọn lẹyin ọpọ awuyewuye, wọn gba pe awọn ọmọbinrin aadọfa ni wọn n wa bayi lẹyin ikolu ọhun.

Awọn ọmọ gbẹ Boko Haram ti n ngbogun ti orilẹede Naijiria fun bi ọdun mẹjọ bayii wọn n beere wọn fun idaduro orilẹede wọn ni agbegbe naa.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Boko Haram ti ngbogun ti orileede Naijiria

Bii ọdun mẹrin sẹyin ni wọn ti ji awọn ọmọdebinrin ọrinlerugba din mẹrin lati ile-iwe kan ni Chibok, eyiti o yọri si ipolongo #BringBackOurGirls ni agbaye.

Awọn bii ọgọrun ninu wọn ṣi wa ninu ahamọ Boko Haram bayi.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹsi: