Ijọba apapọ ti fagile ipade igbimọ alaṣẹ lọsẹ yi

Ipade igbimọ alaṣẹ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Igbimọ alaṣẹ maa n ṣe ipade lọsẹ-ọ-ọsẹ

Wọn ti fagile ipade igbimọ alaṣẹ oriulẹede Naijiria, FEC ti ọsẹ yi eyi ti o yẹ ko waye ni ọjọọru.

Femi Adesina, ti o jẹ oluranlọwọ pataki fun Aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin ati ipolongo, kede eyi ninu atẹjade kan to gbe jade ni ọjọ aje.

Adesina sọ wi pe bi Aare Muhammadu Buhari ati ọpọlọpọ awọn aṣoju ati Minisita se n lọ fun eto pataki kan ni ile igbafẹ Transcorp Hotẹẹli nilu Abuja lọjọru, eyi ti i ṣe ọjọ ipade naa lo sokunfa wiwọgile ti wọn wọgile ipade naa.

Gẹgẹbii atẹjade naa se sọ, "Ipade awọn igbimọ alaṣẹ orilẹede yii ko nii waye ni ọjọru, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu keji ọdun yii"

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari maa ndari iade igbimọ alaṣẹ

"Eleyi waye nitori pe ikopa ti Aarẹ Muhammadu Buhari ati awọn minisita pataki ninu ipade giga apero ti o da le lori ọrọ Chad nilu Abuja".

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: