Boko Haram: Buhari yoo gba itusilẹ gbogbo onde

Aworan aarẹ Buhari nibi ipade pẹlu awọn ti wọn jajabọ lọwọ Boko Haram

Oríṣun àwòrán, BUHARI /TWITTER

Àkọlé àwòrán,

Awon oluko meta lati ile-iwe giga ti Maiduguri( Unimaid) ati awọn obinrin miran bọ lọwọ ikọ Boko Haram laipẹ yii

Awọn olukọ mẹta lati fasiti Maiduguri, Unimaid ati ọkan lara awọn obinrin ti wọn jajabọ lọwọ ikọ Boko Haram ti wa lọdọ aarẹ Muhammadu Buhari lati sepade pẹlu rẹ.

Iroyin fi ye ni pe aago mejila ọsan ọjo aje ni aarẹ Muhammadu Buhari fi asiko igbalejo wọn si.

Lara awọn ti aarẹ Buhari n gbalejo wọn ni osisẹbinrin ni ileesẹ ọlọpa ati ara ilu mẹsan tawọn ikọ eṣinokọku Boko Haram ji gbe nibi ikọlu t'oṣẹlẹ loju ọna Damboa, nilu Maiduguri, nipinlẹ Borno.

Oríṣun àwòrán, BUHARI/TWITTER

Àkọlé àwòrán,

Itusilẹ awọn ti wọn jigbe naa ko sẹhin ọpọlọpọ ifọrọwerọ tẹgbẹ Alagbelebu pupa, (International Committee of the Red Cross), seto rẹ

Aarẹ Buhari, lori itakun agbaye Twitter rẹ, fi lede wipe inu oun dun nitori awọn ti wọn jigbe naa, ti sọ ireti nu, ko to di wipe wọn ri wọn gba pada.

O ni, ‘oun fi dawọn loju wipe gbogbo awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti wọn wa ni panpẹ awọn ajinigbe lawọn yoo gba lagbatan pẹlu awọn ọmọbinrin ileewe Dapchi.

Ti a ko ba gbagbe, itusilẹ awọn ti wọn jigbe naa ko sẹhin ọpọlọpọ ifọrọwerọ tẹgbẹ Alagbelebu pupa, (International Committee of the Red Cross,) seto rẹ, pẹlu atilẹyin aarẹ Buhari.