Ija Kaduna: Ẹmi marun sọnu ninu ija Kasuwan

Aworan ilẹ ijọsin to jona ni Kaduna Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ọpọ igba ni ija igboro maa nbẹ silẹ ni Kaduna, ti wọn si maa njo awọn ile ijọsin ni ina

Eniyan marun ti padanu ẹmi wọn, ti ọgọọrọ mii si farapa ninu isẹlẹ to waye lagbegbe Kasuwan nipinlẹ Kaduna.

Iroyin naa sọ wipe agbegbe tikọlu naa ti sẹlẹ ko jinna si aarin gbungbun ilu Kaduna to lọ si ipinlẹ Plateau, Nasarawa ati Benue.

Awọn eeyan kan to bawọn akọroyin sọrọ ni awọn ko lee sọ ohun to sokunfa aawọ ọtun yi.

Wọn fikun wipe, awọn ọlọpa to tete koju isẹlẹ naa, ni ko jẹ ki ọrọ naa di ti ija ẹsin.

Nibayi, Gomina ipinlẹ Kaduna, Malam Nazir El-Rufai ti pasẹ fun awọn eleto aabọ ipinlẹ naa lati se ofin toto isẹlẹ naa, ki wọn si fi awọn to wa nidii ọrọ naa jofin.