Ibuba Manchester United, Old trafford ni Usain Bolt nlọ

Usain Bolt elere ori papa ni Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Laipẹ yii ni Bolt kede wipe oun ti buwọlu iwe adehun pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu kan

Gbajugbaja elere ori papa ni, Usain Bolt ti kede wipe papa isire Old Trafford ni oun yoo ti gba ifẹsẹwọnsẹ bọọlu akọkọ lẹyin to fi ẹyin ti ninu ere sisa.

Lọjọ isẹgun ni Usain bolt kede ọrọ yii lori ikanni ayelujara facebook rẹ.

Usain Bolt salaye wipe oun yoo wa lara ikọ ere bọọlu Soccer aid fun ajọ to n mojuto ọrọ awọn ewe lagbaye, UNICEF ti yoo gba bọọlu ikowojọ kan ni papa isire Old traford, iyẹn ibuba ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ni ilẹ Gẹẹsi lọjọ kẹwa osu kẹfa.

Laipẹ yii ni Usain bolt kede wi pe oun ti buwọlu iwe adehun pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu kan to si fi orukọ bo lasiri.

Ọjọ ti pẹ ti Usain Bolt ti n gbimọran lati bẹrẹ oowo bọọlu gbigba jẹun lẹyin to ba fi ere sisa silẹ; bẹẹni ikọ agbabọọlu Manchester United wa lara ẹgbẹ agbabọọlu ti Bolt papaa ti sọ lawọn akoko kan sẹyin wipe o wu oun lati darapọ mọ.

Ko si ẹni to lee sọ o boya apẹrẹ ibi ti ori ngbe bolt lọ ni ifẹsẹwọnsẹ to kede yii yoo je.