Benue: Ọwọ ologun tẹ darandaran mẹwa to n ba oko jẹ

Awọn afunrasi ti ọwọ ba joko lori ilẹ niwaju ologun Image copyright @HQNigerianArmy
Àkọlé àwòrán Ohun ija lorisirisi ni wọn ka mọ awọn afunrasi naa lọwọ

Ọwọ awọn ologun ti tẹ awọn darandaran Fulani mẹwa kan ti wọn n ba oko oloko jẹ nipinlẹ Benue, lẹkun aringbungbun ariwa orilẹede Naijiria.

Ohun ija lorisirisi ni wọn ka mọ awọn afunrasi naa lọwọ.

Ọwọ awọn ọmọogun to n saayan eto abo 'Operation Ayem Akpatuma' tẹ awọn afurasi naa nileto Tse-Tigir ati Tse-Ndugh.

Awọn ologun tun ka awọn ohun ija oloro lorisirisi mọ awọn darandaran Fulani ọhun lọwọ.

Alupupu marun, ada meji, oogun abẹnu gọngọ ati ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira ni wọn gba lọwọ awọn afurasi naa

Atẹjade kan eyi ti alukoro fun ileesẹ ọmọ ogun lorilẹede Naijiria, Ọgagun Texas Chukwu fi sita nilu Abuja salaye wi pe, awọn afunrasi naa bẹlu'gbo nigba ti wọn ri awọn ọmọogun naa.

"Lara awọn ohun ti wọn gba lọwọ awọn afunrasi naa ni alupupu marun, ada meji, oogun abẹnu gọngọ ati ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira."

Alukoro ileesẹ ologun oriilẹ lorilẹede Naijiria ni awọn ọmọogun yoo ri daju wi pe gbogbo awọn kọlọransi ti wọn baa kẹẹfin ni wọn fi panpẹ ofin gbe.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: