Ile ise ologun jẹwọ wipe lootọ l'awọn ko si ni Dapchi

Ile ẹko Dapchi Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn eniyan o tete mo wi pe awọn ọmọ ile ẹko naa sonu

Ile iseẹ oloogun lorilẹẹde Naijiria ti gba wi pe looto ni awọn tiko ọmọogun kuro ni agbegbe Dapchi lasiko ti Boko Haram fi ya wọ ibẹ lati ji akẹkọ obirin to le ni ọgọrun gbe lọsẹ to kọja.

Wọn ni ipa awọn ko ka pipese abo fun gbogbo awọn ile ẹko to wa ni agbegbe naa lo faa.

Lọsẹ to kọja ni Gomina Yobe, Ibrahim Geidam sọ wi pe lẹyin nkan bii ọsẹ kan ti awọn ọmọ ogun kuro ni awọn agbebọn Boko Haram kolu agbegbe naa.

Asoju ijọba Naijiria mi titun de Dapchi

'Irọ ni, ko si ologun kankan ni Dapchi'

Ẹwẹ, ile isẹ ọmọ ogun ofurufu ni awọn ti se afikun iye baalu ogun ti won fi'n wa awon ọmọ ile ẹko Dapchi to sọnu.

Ọse kan kọja ki ijọba to gbe igbese lati bẹrẹ si ni wa awọn ọmọ ile ẹko Government Girls Technical College Dapchi ti Boko Haram jigbe.

Aarẹ Buhari ni gbogbo ohun to ba gba lawọn yoo se lati se awari awọn ọmọ ile ẹko naa.

Saaju isẹlẹ yii, lọdun 2014 ni Boko Haram yabo ile ẹko awọn obirin nilu Chibok nibi ti wọn ti ji obirin to le ni irinwo gbe.

Wọn sọ ọpọ di iyawo ti wọn si lo awọn miran gẹgẹ bi iransẹ iku nipa siso ado oloro ipaniyan mọwon lara.

Awọn ẹniyan ti bẹrẹ si ni se apejuwe isẹlẹ Dapchi yi pẹlu ti Chibok to waye lọdun mẹrin sẹyin.