Ọwọ ọlọpaa tẹ eeyan mẹwa lori wahala Kaduna

Aworan ọkọ ati ile ti wọn so ina si

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Lara ipenija ipinlẹ Kaduna ni ikọlu darandaran.Okunrin yi'n nawo si ọkọ ti wọn so ina si labule Barkin Kogi lọjọ kẹrinlẹlogun osu keji ọdun 2017.

Ọwọ ọlọpaa ti tẹ eeyan mẹwa lori wahala to waye ni ilu Kaduna, lẹkun iwọ oorun orilẹede Naijiria, ni ọjọ aje.

Alukoro fun isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kaduna, Muktar Aliyu salaye fun BBC wi pe, ileesẹ ọẹọpaa si wa lẹnu iwadi lati mọ ohun to sokunfa wahala naa.

Eniyan meje lo padanu ẹmi wọn ti awọn mẹẹdogun miran si tun fara gb'ọgbẹ nigba ti ija kan bẹ silẹ lagbegbe Kasuwan Magani ni ijọba ibilẹ Kajuru ni ipinlẹ Kaduna.

Alukoro fun isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kaduna, Muktar Aliyu salaye wi pe, 'A o mo ohun to fa ija naa sugbọn a ti dẹkun rẹ.

"A si ti gbe igbesẹ ki wahala naa maa baa tan ka de awọn agbegbe miran ni ipinle yi."

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Ọlọpa ni ko si ẹni lee sọ boya ọrọ ẹsin lo sokunfa wahala naa

Biotilẹ jẹ wi pe awọn kan ti ọrọ naa soju wọn sọ fun BBC pe wahala bẹ silẹ nigba ti ọmọbirin ẹya Gwari kan yi ẹsin pada lati Kristẹni si Musulumi nitori ọrekunrin rẹ.

Amọsa, ileesẹ ọlọpaa salaye wipe, "A ko le fidi ọrọ yii mulẹ wi pe ayipada ẹsin eeyan kan lati Kristẹni si Musulmi tabi ẹsin miran lo da ija naa silẹ.

"Olukuluku lo ni ẹtọ lati se ẹsin to ba wu u. Eleyi ko yẹ ko fa ija rara".

Irin Kasuwan Magani si aarin gbungbun Kaduna to kilomita mẹrindinlọgbọn o si jẹ oju ọna ti eeyan le gba lọsi apa guusu Kaduna, Plateau, Nasarawa ati ipinlẹ Benue.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: