Ijinigbe ile ẹko Dapchi: Oun ta mọ nipa rẹ

Aworan ile-iwe Daphchi nibi ti wọn ti ji ọgọọrọ akẹẹkọ gbe - 23 02 2018

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Ile-iwe Daphchi ni akẹẹkọ to le ni ẹẹdẹgbẹrun

Ijinigbe awọn ọmọ ile ẹko Dapchi to le ni ọgọrun ni iwọ oorun ariwa Naijiria ti'n kọni lominu.

A mọ wipe ikọ awọn ọmọ agbebọn, to seese ki wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ Boko Haram yabo ilu Dapchi lọwọ irọle ọjọ Aje l'ọjọ kọkandinlogun osu keji.

Wọn kọri si ile ẹkọ Government Girls Science and Technical College, ti wọn si kuro lẹyin igba diẹ.

Ni ibẹrẹpẹpẹ, wọn ni ọpọ awọn ọmọbirin naa lo ti rari bọ, ati wi pe wọn ko ji enikankan gbe. Sugbọn lẹyin ọse kan awọn alasẹ gba wipe lootọ ni awọn Boko Haram ji awọn ọmọ naa gbe.

Ki wa lo'n sẹlẹ gaan?

Ki lo fa a ti a ko fi mọ ohun to nsẹlẹ gaan?

Olukọni kan ti o ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin ikọlu naa pe wọn o ji ẹnikankan gbe.

O ni ounjẹ ni awọn onisunmọmi naa n wa ati wipe wọn ko fẹ ji ẹniyan gbe. O ni awọn ọmọbirin naa sa wọ igbo, nibi ti wọn sapamọ si.

Oniroyin BBC Halima Umar, to fidi kalẹ si Abuja ni o jọ pe ijọba ko tete gba isẹlẹ yii wọle ati wipe lẹyin orẹyin ni wọn to gba wipe wọn ji awọn ọmọbirin naa gbe.

Amọ, ọrọ naa tun daru si nigbati awọn ẹka ijọba ati ile isẹ ologun bẹrẹ si ni fon fere ọtọọto, debi wipe wọn kede pe wọn doola ẹmi awọn ọmọbirin kan lasiko igba ti ko si ẹnikẹni to kọkọ gba wipe ijinigbe waye.

Ọmọbirin meloo ni wọn jigbe?

Okunfa ariyanjiyan laarin awọn obi awọn omọ to sọnu, ati awọn alase ni iye ọmọ ile ẹkọ to sọnu ni pato.

Awọn ọbi ko janu kuro lori wipe o le ni ọgọrun akẹẹko ti won jiigbe ni ile ẹko naa, ninu ọmọ ile ẹko toto ẹẹdẹgbẹrun-le-mẹrindinlọgbọn

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Awọn ẹbi ati ara awọn woye ibi ti wọn yoo ti ri awọn ọmọ naa

Awọn alasẹ ni iye ẹniyan ti wọn ji gbe ko ju ogoji lọ ati wipe ọpọ to sa wọ inu igbo ko ni pe pada de.

Sugbọn lẹyin atotonu, ijọba pada sọwipe iye awọn ọmọ to sọnu ni ọgọrun ati mẹwa.

Kini ifarawe isẹlẹ yii ati ijinigbe awọn ọmọ ile-iwe Chibok?

Will Ross, to jẹ olootu ile-isẹ BBC World Service Africa, foju sunnukun wo ifarajọ to wa laarin isẹlẹ naa ati ti ijinigbe awọn ọmọ Chibok, losu Kẹrin, ọdun 2014 to sẹlẹ ni agbeegbe Chibok ti ko jina si Guusu- Ila oorun Dapchi.

Ninu ọrọ rẹ, oni nigba tawọn ọmọ Chibok, bi ijọba se dakẹ lori ọrọ naa niyẹn, koto di wipe wọn sọ wipe awọn ọmọ orinlẹlugbadinmẹrin(276), lawọn ọmọ Chibok to sọnu.

Ọdun mẹrin ti kọja, gbogbo agbaye tun ti n wo bi awọn olootu ijọba se n s'iwadi lori isẹlẹ Daphchi, ti awọn obi si n ke roro lori bii ijọba o se kọbi ara si isẹlẹ naa.

Ero awọn eniyan ni wipe ijọba to wa lode yii, ko kọ ẹkọ kankan lara isẹlẹ to sẹlẹ lọdun mẹrin sẹhin, atiwipe ọgọrun ninu awọn ọmọ Chibok naa, lo si wa ni ahamọ awọn Boko Haram ti wọn tun fi wa ji awọn ọmọ Daphchi yii gbe.

Awọn eniyan n wo o boya wọn yoo ri awọn ọmọ ti wọn jigbe yii gba pada.

Ki lo de ti ko si aabo to peye ni ile-iwe?

Iroyin fi lede wipe, eto aabọ nile iwe to wa ni Yobe mẹhẹ, bi o tilẹ jẹwipe agbeegbe yii ni wọn ti ji awọn ọmọ Chibok gbe ni ọdun 2014, ti awọn obi si n ran awọn ọmọ wọn lọ sile iwe lagbeegbe naa.

Akọrọyin BBC to wa labuja sọwipe, awọn obi n ran awọn ọmọ wọn lọ si ile-iwe nitoriwipe wọn gbagbọ ninu ijọba aarẹ Buhari ati gbogbo ipolongo awọn ọmọgun ilẹ Naijiria wipe awọn ti bori ikọ Boko Haram.

A tun mọ wipe awọn ologun wa, to n sọ ọna to lọ si ilu naa, nitori gomina ipinlẹ Yobe, sọwipe awọn agbebọn naa, sọsẹ lẹyin wakati diẹ tawọn ọmọogun kuro loju popo ti won n sọ.

Ile-isẹ ologun ilẹ yii ti jẹwọ wipe looto ni awọn ko awọn ọmọogun kuro ni agbeegbe Daphchi- awọn ọmọ Naijiria si n bere, wipe ta lo ni kii wọn ko awọn ọmọogun kuro loju ọna, ni wakati diẹ sigba tawọn ajinigbe wa ko awọn ọmọ naa.

Kilode ti won ko tii ri awon omo dapchi yii?

Lẹyin ọse kan ni ijọba orilẹede Naijiria to panupọ wipe lootọ ni pe awọn ọmọ sọnu ati wipe awọn ti bẹrẹ lati wa awọn ọmọ naa lawari.

Aarẹ Muhammadu Buhari sọwipe ọmọogun ori ilẹ ati ti ofurufu ni awọn yoo lọ lati sawari awọn ọmọ Daphchi ti wọn ji gbe naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Iyoku awon ẹru awọn ọmọ naa wa nile ẹkọ wọn

Sugbọn ọkan lara awọn iwe iroyin lorilẹede Naijira, Daily Trust, sọwipe idaji awọn ọmọ naa ni awọn ajijagbara naa ti gbe kuro lorilẹede Naijiria lọ si orilẹede Niger to sun mọ Naijiria.

Amọ, iroyin kan sọwipe, ti wọn ba si wa ni orilẹede Naijiria, igbo Sambisa lawọn ajinigbe naa yoo ko awọn ọmọ lọ, nitori wipe igbo yii nikan lo tobi to bẹẹ, ti wọn le ko awọn ọmọ naa pamọ si.

Atiwipe ibẹ ni olu-ibugbe wọn, ibẹ ni wọn si ko awọn ọmọ Chibok pamọ si.

Ijọba Naijiria sọwipe awọn ti bori ikọ Boko Haram- njẹ otito ni?

Ọgaagun Roger Nicholas, to dari ikọ to n koju Boko Haram lagbegbe iwọ-oorun ariwa orilẹede Naijria sọ wipe awọn ti bori ikọ Boko Haram ni osu Kini, ọdun yii.

Amọ, ijinigbe ọlọgọọrọ yii safihan alaye miran.

Akọroyin fun ọrọ eto aabo pẹlu BBC Africa, Tomi Oladipo ti figba kan toka ọrọ ijoba orilẹede Naijiria to sọ wipe awon ti bori ikọ Boko Haram.

O salaye wipe ọrọ naa tapasi gbogbo iye owo ribiribi ti wọn n naa lori ohun ija ti wọn n ko wọle si orilẹede Naijiria, ati wipe ikọ naa n sọọsẹ ni agbeegbe Lake Chad.

Amọ, wọn fi gba kan sọ fun BBC wipe wọn ti fẹrẹ mu olori ikọ Boko Haram ki oto di wipe wọn se ikọlu tuntun yii.

Nigba ti awọn ọmọogun yoo fi de ibi ti wọn ni olori ikọ Boko Haram lugọ si, o ti na papa bora.

Ile-ise ologun ile Naijiria ti sọ wipe ko si otitọ kankan ninu iroyin naa.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: