APC: Afikun ba saa Oyegun gẹgẹbii alaga

Oloye Odigie Oyegun Image copyright @APCNigeria
Àkọlé àwòrán Aimoye aawọ lo nwaye ninu ẹgbẹ oselu APC labẹ́nu

Igbimọ alasẹ ẹgbẹ oselu APC ti fontẹ lu saa igbimọ amusẹya ẹgbẹ oselu naa, eyiti Oloye John Odigie Oyegun ko sodi, fun ọdun kan gbako.

Nibi ipade igbimọ alasẹ ẹgbẹ to waye loni ni wọn ti se ipinnu naa.

Nigba to nsọrọ lẹyin ipade naa, gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello ni, saa tuntun naa bẹrẹ lọgbọnjọ osu kẹfa ọdun 2018.

"Taa ba wo akoko to ku fun ẹgbẹ APC lati seto idibo abẹnu rẹ ati ipade apapọ ẹgbẹ, to fi mọ eto ipẹtu saawọ ti wọn gbe le asaaju wa, Bọla Tinubu lọwọ, a ko lee wọnu eto idibo gbogbo gboo lọ bayi pẹlu gbọnmisi omioto to wa ninu ẹgbẹ."

"Idi ree taa fi se afikun saa igbimọ alasẹ ni gbogbo ẹka ẹgbẹ oselu APC fun osu mejila gbako bẹrẹ lati ọgbọnjọ osu kẹfa ọdun 2018"

Image copyright @APCNigeria
Àkọlé àwòrán Laipẹ yi ni aarẹ Muhammadu Buhari yan Tinubu lati yanju aawọ abẹnu APC

Awọn iroyin eke lawọn ileesẹ iroyin ngbe jade nipa APC

Nigba to nfesi lori isẹlẹ yii, alaga ẹgbẹ oselu APC, Oloye John Oyegun ni abọ ipade alasẹ ẹgbẹ APC ti dojuti awọn eeyan to nsasọtẹlẹ ibi nipa oun pe wọn yoo yọ oun nipo.

Oloye Oyegun kede eyi nigba to nbawọn akọroyin ile ijọba nilu Abuja sọrọ lẹyin ipade igbimọ alasẹ ẹgbẹ APC eyiti aarẹ Muhammadu Buhari dari nilu Abuja.

"Abọ ipade naa rẹwa, osi dun mọni ninu. Amọ awọn akọroyin lo nkọ awọn iroyin to wu wọn nipa ẹgbẹ oselu APC, ti wọn si tun nbu mọ isẹlẹ to n waye ninu ẹgbẹ naa."

O fikun pe ọpọ iroyin ti wọn ntan kalẹ lori ẹrọ ayelujara ati loju ewe awọn iwe iroyin lẹnu lọọlọ yi lo jinna sootọ.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: