Ile asofin Kwara: Owo ifẹyinti d'opin f'awọn gomina ana

Gbọngan ile asofin ipinlẹ Kwara Image copyright @kwhanigeria
Àkọlé àwòrán Aarẹ ile asofin agba ni Naijiria jẹ gomina tẹlẹri nipinlẹ Kwara

Ile asofin ipinlẹ Kwara ti fontẹ lu atunṣe aba ofin kan to n tako igbesẹ sisan owo ifẹyinti f'awọn gomina ana atawọn igbakeji wọn pẹlu awọn eeyan mii to dipo oṣelu mu lẹyin ti saa wọn ba pari.

Ile gbe igbesẹ yii lẹyin ti igbimọ ile to wa f'eto idaleesẹ silẹ ati ọrọ osisẹ ọba gbe abọ rẹ kalẹ nibi ijoko ile asofin naa to waye nilu Ilọrin.

Igbakeji olori ile, Sẹgilọla Abdulkadir lo daba wipe ki wọn gba abọ igbimọ naa wọle, ti gbogbo awọn asofin naa si fọwọsii.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Aba naa, ti gomina ipinlẹ Kwara, Abdulfatai Ahmed fi sọwọ sile asofin naa, lo wa lati se agbeyẹwo ofin kan eyi to buwọlu igbesẹ sisan owo ifẹyinti fawọn gomina tẹlẹ nipinlẹ naa tawsn igbakeji wọn lẹyin ti saa wọn ba pari.