Alaafin Ọyọ bí ìbejì lẹ́ẹ̀mẹta láàrin oṣù mẹ́jọ

Alaafin Ọyọ bí ìbejì lẹ́ẹ̀mẹta láàrin oṣù mẹ́jọ

Aláàfin ìlú Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi Kẹta tún ti bí ìbejì mi i.

Ìgbà kẹta nìyíì ti yóò bí ìbejì l'ọ́dún 2018 nìkan ṣoṣo.

Bákan nàá ló ti bí ìbẹta rí.

Ọ̀kan lára àwọn olorì rẹ̀, Anuoluwapọ Adeyẹmi ló tún bí ìbejì ọkùnrin kan àti obìnrin láìpẹ́ yìí, èyí tó sọ ọ́ di ìkẹta láàrin oṣù mẹ́jọ.

Àwọn méjì kan ti bi ìbejì l'ọ́dún 2018.

Àwọn ni Olori Badirat Ọlaitan Adeyẹmi tó bí ìbejì ọkùnrin nínú oṣù Kẹta.

Oríṣun àwòrán, @queenola2/Instagram

Àkọlé àwòrán,

Olori Badirat Ọlaitan Adeyẹmi tó bí ìbejì ọkùnrin nínú oṣù Kẹta.

Bákan nàá ni Olorì Memunat Omowumi Adeyẹmi tó bí ìbejì ọmọbìnrin méjì nínú oṣù Kẹta bákan nàá.

Oríṣun àwòrán, @queenomohone/Instgram

Njẹ ki wa ni asiri agbara Alaafin, ẹni to ti le ni ọgọrin ọdun, to fi nbi ibeji ati ibẹta ni ọpọ igba?

Èyí ni ìbéèrè tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Yorùbá n bèérè.

Ọmọọbabinrin Alaafin, Olubunmi Labiyi bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ nínú fọ́nrán tó wà l'ókè.