Awọn eeyan sọ tẹnuwọn nipa iṣuna ipinlẹ Eko f'ọdun 2018

Awọn eeyan sọ tẹnuwọn nipa iṣuna ipinlẹ Eko f'ọdun 2018

Ọkan o jọkan ọrọ ni araalu ti n sọ lori aba isuna oni trillionu kan naira fun ọdun 2018 ti ijọba ipinlẹ Eko buwọlu.

Igbagbọ ọpọlọpọ awọn eniyan to ba BBC Yoruba sọrọ niwipe ko ti i si ipinlẹ kan ti o gbiyanju aba isuna ti owo rẹ to trillionu kan naira ri lorillede Naijiria.

Awọn eniyan ilu Eko ti o ba ikọ iroyin wa sọrọ fi ero ọkan wọn han lori aba naa.