Tinubu yoo fesi lori ipade alaṣẹ ẹgbẹ APC to ṣafikun asiko fun Oyegun

Aarẹ Buhari pẹlu oloye John Odigie nibi ipade

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Àkọlé àwòrán,

Aimoye aawọ lo nwaye ninu ẹgbẹ oselu APC labẹ́nu

Asiwaju fun ẹgbẹ oselu APC lorilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti salaye wi pe ọ̀rọ̀ ko tii to sọ̀ bayii lori ipade igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ oselu APC eleyi ti fikun asiko ti alaga ẹgbẹ oselu naa, Oloye John Oyegun yoo lo lori oye.

Lọjọ isẹgun lawọn ọmọ igbimọ naa fi ọdun meji ku saa Oyegun gẹgẹbi alaga ẹgbẹ oselu naa.

Ọgbẹni Tunde Rahman to jẹ agbẹnusọ fun Asiwaju Bọla Tinubu ni eekan ẹgbẹ oselu APC naa si n fi oju sunukun wo ọrọ naa ati pe laipẹ laijinna, yoo sọrọ.

Ọgbẹni Rahman sọ fun BBC Yoruba wi pe wọn ko tii fi abajade igbimọ naa to agba oloselu naa letilati olu ileesẹ ẹgbẹ oselu ọhun nilu Abuja , ati wipe awọn ko fẹẹ fesi lori ọrọ awawi.

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Àkọlé àwòrán,

Laipẹ yi ni aarẹ Muhammadu Buhari yan Tinubu lati yanju aawọ abẹnu APC

Sugbọn, agbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu APC, Bolaji Abdullahi sọ wi pe aigbọ agbọye lori eto oṣelu nipinlẹ Kogi ni o ṣe okunfa lẹta ifẹhonuhan ti asiwaju Bọla Tinubu kọ si aarẹ orilẹede Naijiria.

Abdullahi sọ fun ileeṣẹ BBC Yoruba ninu ifọrọwanilẹnuwo lori bi igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu APC ti fontẹ lu saa igbimọ amusẹya ẹgbẹ oṣelu naa, eyi ti o sun akoso oloye John Oyegun fun ọdun kan gbako, nibi ipade igbimọ alasẹ ẹgbẹ oselu ọhun to waye nilu Abuja lọjọ iṣẹgun.

Ninu ọrọ tirẹ lori ọrọ naa, Joe Igbokwe, agbẹnusọ nigbakanri fun ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko sọ wi pe Asiwaju Tinubu ti jeburẹ ni o fun oloye Oyegun ni anfaani lati ri Afikun asiko, ati wipe eyi tumọsi wipe awọn mejeeji ti tu ara wọn ninu gẹgẹbi agbaagba oloṣelu ninu ẹgbẹ APC.

Àkọlé àwòrán,

Asiwaju Tinubu nfehonu han lori eto oselu labe Odigie

O wi siwaju sii wipe, "ti asiwaju Tinubu ba gba iṣẹ kan ṣe, ko nii kuna ninu rẹ ati wipe Aarẹ Buhari ti kin in lẹyin nibi ipade awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa nibiti o ti paṣẹ fun awọn ọmọ ẹgbẹ oselu naa lati f'ọwọsowọpọ pẹlu Asiwaju Tinubu fun aaye lati pẹtu si awọn aawọ abẹle ninu ẹgbẹ oselu naa.

Aarẹ Buhari sọrọ pe, "Taa ba wo akoko to ku fun ẹgbẹ APC lati seto idibo abẹnu rẹ ati ipade apapọ ẹgbẹ, to fi mọ eto ipẹtu saawọ ti wọn gbe le asaaju wa, Bọla Tinubu lọwọ.

"A ko lee wọnu eto idibo gbogbo gboo lọ bayi pẹlu gbọnmisi omioto to wa ninu ẹgbẹ."

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: