Ijinigbe ni Dapchi: Igbimọ ẹlẹni mejila n kọri si Yobe

Buhari n buwọlu iwe

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Àkọlé àwòrán,

Aadọfa ọmọ ni ko tii di riri ni Yobe

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti gbe igbimọ ẹlẹnimejila kan kalẹ lati sisọ loju eegun awọn ohun to rọ mọ jiji ti awọn agbebọn ji aadọfa akẹkọ ileewe girama awọn obinrin ni ilu Dapchi, ipinlẹ Yobe gbe.

Igbimọ ọhun eleyi ti alaga rẹ yoo jẹ ọgagun agba ti ipo rẹ ko kere ju Major General lọ yoo ni olori eto gbogbo nileesẹ ologun oriilẹ, oriomi ati oju ofurufu gẹgẹbi ọmọ igbimọ.

Bakanaa ni asoju illesẹ ọtẹlẹmuyẹ orilẹede Naijiria NIA, ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ ọmọogun (DIA), ileesẹ ọlọpaa, ileesẹ abo ara ẹni laabo ilu, Civil defence ati asoju meji lati ijọba ipinlẹ Yobe ati ọfiisi alamojuto agba lori ọrọ aabo lorilẹede Najiria, ONSA pẹlu yoo kun wọn ninu igbimọ naa.

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Àkọlé àwòrán,

Ọpọlọpọ lo n kọminu lori ohun ti wọn pe ni aibikita to ijọba lori ọrọ awọn akẹkọ Dapchi

Alamojuto agba fun ọrọ abo , NSA, Ọgagunfẹyinti Babagana Monguna lo gbe igbimọ naa kalẹ.

Lara awọn ohun ti igbimọ yii yoo maa mojuto ni fifi idi awọn isẹlẹ to rọgba yii jiji ti wọn ji awọn akẹkọ girama Dapchi gbe; bẹẹni wọn yoo tun se ayẹwo finifini lori iduro deede eto abo ni ilu Dapchi ati ileewe gira naa saaju isẹlẹ naa, ki wọn si tun gbe amọran kalẹ lori awọn igbesẹ to lee tọ ijọba sọna lori ibi ti awọn ọmọ naa lee wa ati ọna lati tu wọn silẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Igba meji ọtọọtọ ni ijọba apapọ ti ran ikọ lọ si ipinlẹ Yobe lori ọrọ awọn ọmọ Dapchi

Igbimọ naa yoo tun mu aba wa lori awọn ọna lati pinwọ irufẹ isẹlẹ bẹẹ ni ọjọ iwaju.

Ọjọ kẹẹdogun osu kẹta ọdun 2018 ni wọn fun igbimọ naa da lati fi j'abọ isẹ rẹ eleyi ti yoo bẹrẹ ni ọjọọru ọjọ kejidinlọgbọn osu keji.

Ni ọjọ aje, ọjọ ọjọ kskandinlogun osu keji ni awọn agbebọn sigun kọlu ileewe Girama awọn obinrin to wa ni ilu Daphi, ipinlẹ Yobe lẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: