Buhari da aba ofin fun idasilẹ Peace Corps s'igbo

Aarẹ Buhari n buwọlu iwe kan

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Àkọlé àwòrán,

Ara awọn idi ti Aarẹ Buhari la kalẹ ni ọda owo, awo olokun

Ọpọ ayọ lo gba agbo awọn omilẹgbẹ ọdọ ti wọn wa lajọ Peace Corps lorilẹede Naijiria lọdun 2017 ti iroyin jade wipe ileegbimọ asofin apapọ lorilẹede Naijiria ti buwọlu aba naa.

Amọsa, ọrọ ti ba ibomiran yọ bayii pẹlu bi Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe kuna lati buwọlu aba naa ko lee d'oun.

Ninu iwe kan eyi to kọ si ileegbimọ asojusofin, Aarẹ Muhammadu Buhari ni, laisi ohun to ṣe ẹsẹ, ẹsẹ kii dede sẹ o! O ni awọn idi meji jankan-jankan lo faa ti oun ko fi ni lee buwọlu aba naa.

Oríṣun àwòrán, @PeaceCorpsNG

Àkọlé àwòrán,

Ala ọpọ awọn ọmọ ajọ Peace Corps lati bẹrẹ sini gba owo osu dabi eyi ti o ti f'ori sanpọn bayii

Idi ti Aarẹ Buhari fi da abadofin idasilẹ ajọ Peace Corps sigbo

Aarẹ Buhari ni idi akọkọ ti ala awọn omilẹgbẹ ọdọ to wa labẹ ajọ naa ko fi tii lee sẹ bayii ni wi pe, oniruru awọn ileesẹ alaabo lo ti wa nilẹ ti wọn n se isẹ kannaa pẹlu eyi ti wọn la kalẹ fun ajọ Peace Corps lati maa se ninu abadofin naa.

Aarẹ ni eyi lee fa dukuu lẹka eto abo lorilẹede Naijiria laarin awọn ajọ alaabo gbogbo.

Idi keji ti Aarẹ Buhari tun la kalẹ ni ti ọda owo, awo olokun.

Aarẹ Buhari ni pẹlu ipo aisi owo to gbode kan lorilẹede nayijiria bayii ati kaakiri agbaye, yoo nira diẹ lati tun se idasilẹ ajọ kan ti yoo tun maa gba lara owo ijọba ti ko to tẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, @nassnigeria

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Buhari kọwe sawọn asofin apapọ, o ni ko sowo lati gbọ bukata ajọ Peace Corps

Pẹlu igbesẹ yii, ko si ẹni to mọ ohun to kan bayii fun ajọ naa, paapa julọ awọn ọdọ ti wọn darapọ mọ ajọ naa lẹyin ti ireti ti wa pe ajọ naa yoo di eyi ti awọn oṣiṣẹ rẹ yoo maa gba owo-osu lẹyin ti awọn asofin apapọ ti buwọlu ni ọdun 2017.

Ṣaaju akoko yii gan ni awọn afarajọ dukuu ti bẹrẹ si nii waye laarin ajọ naa ati ileesẹ ọlọpa, to fi mọ ajọ abo araẹni laabo ilu(Civil Defence) lawọn ipinlẹ kan ati orilẹede Naijiria lapapọ.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: