Ijinigbe Dapchi: Dogara kọminu lori wahala ologun ati ọlọpa

Olori Ileegbimọ asofinsoju lorilẹede Naijiria, Yakubu Dogara Image copyright @YakubDogara
Àkọlé àwòrán Asofin Dogara ni oun wa ni ilu Dapchi lọjọ ti isẹlẹ ijinigbe awọn ọmọ naa sẹlẹ

Olori Ileegbimọ asofinsoju lorilẹede Naijiria, Yakubu Dogara, ti koro oju si awọn ọrọ to njade lati ileesẹ ọmọogun oriilẹ ati ileesẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria ninu eyi ti ileesẹ mejeeji fi n yọ ara wọn kuro ninu ẹbi ọrọ isẹlẹ to sẹlẹ si awọn akẹkọbinrin nileewe girama kan nilu Dapchi, nipinlẹ Yobe lẹkun ila oorun ariwa orilẹede naa.

Ninu atẹjade kan eyi to fi sita, asofin Dogara nidipo awuyewuye sisọ oko ẹbi si ara wọn ohun to yẹ ko waye laaring ileesẹ alaabo mejeeji naa ni ajọsepọ ati igbọraẹniye to dan mọran eleyi ti yoo lee jẹ ki ọna la fun igbesẹ lati se awari awọn akẹkọ ti wọn ji gbe naa.

"Awọn ọrọ ti wọn sọ wipe ileesẹ ọmọogun ati ọlọpaa sọ ninu eyi ti wọn ti gbiyanju ati yọ ara wọn kuro ninu ẹbiisẹlẹ ikọlu ileewe giram to wa nilu Dapchi ati bi wọn se ji awọn akẹkọ gbe lọ nibẹ ko bojumu rara.

Image copyright @nassnigeria
Àkọlé àwòrán Ileegbimọ asofinsoju ko ni fi ojuure wo ileesẹ alaabo

Ileegbimọ asofinsoju ko ni fi ojuure wo ileesẹ alaabo yoowu ti aje isẹlẹ yii ba si mọ lori. Gbogbo awọn ileesẹ alaabo ni yoo jẹjọ ẹbi isẹlẹ yii."

Olori ile asofinsoju lorilẹede Naijiria, Asofin Dogara ni orilẹede Naijiria ko tii bọ ninu wahala ti awọn ti wọn jigbe ni agbegbe Chibok bayii, eleyi to ni o yẹ ko jẹ odiwọn ikiyesara fawọn ileesẹ alaabo lati pese abo to gbopọn fun gbogbo awọn ileewe to wa lẹkun ila orrun ariwa orilẹede Naijiria.

Aṣofin Dogara ni oun wa ni ilu Dapchi lọjọ ti isẹlẹ ijinigbe awọn ọmọ naa sẹlẹ ati wi pe oun tete gbera wa silu Eko ni ki o to di wipe ipe bẹrẹ si nii wọle fun oun pe wọn ti ji awọn akẹkọ naa gbe lẹyin ti awọn agbebọn Boko Hara kọlu ileewe naa.

"Ọgbọn ni awọn agbebọn naa lo nigba ti wọn de ileewe naa. N se ni wọn tan awọn akẹkọ naa wi pe ologun lawọn"

O wa rọ ijọba apapọ lati seto bi awọn akẹkọ naa yoo se di riri ki wọn si pese akọtun aabo to gbopọn fun awọn ileewe ni ipinlẹ Borno, Yobe atawọn ipinlẹ miran ti o wa lẹkun naa.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: