Peace Corps: Ileesẹ ọlọpaa lo wa nidi ọrọ wa

Awọn ọmọ ikọ peace corps duro bi ologun

Oríṣun àwòrán, PeaceCorpsNG

Àkọlé àwòrán,

Ajọ naa ni ohun to kan ni lati pada si ile gbimọ asofin apapọ

Ajọ Peace Corps ti fi ẹsun kan ileesẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria wipe awọn gan an lo wa nidi bi Aarẹ Buhari se kuna lati buwọlu abadofin idasilẹ ajọ naa.

Alukoro ikọ alalaafia lorilẹede Naijiria, arabinrin Millicent Umoru lo sọ eyi di mimọ ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba.

Lọjọ isẹgun ni Aarẹ Muhammadu Buhari kọ iwe ransẹ sile asofin agba wi pe oun kolee buwọlu abadofin idasilẹ ikọ alalafia Peace Corps ti wọn fi sọwọ si oun.

Ajọ naa ni ohun to kan ni lati pada si ile igbimọ asofin apapọ lati mọ boya ọna abayọ wa fun aba ajọ naa.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Dida abadofin wa sigbo, ko lee di wa lọwọ

" Ohun to han si ita gbangba ni wipe ileesẹ ọlọpaa ko fẹ ki eegun ajọ Peace corps suyọ. A tilẹ gbọ nipa bi ọga agba ileesẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria se bura wi pe gbogbo ipa oun loun yoo sa lati rii pe ajọ naa wọlẹ."

Ikọ alalafia naa ni bio tilẹ jẹ wipe aarẹ ko buwọlu aba idasilẹ rẹ, sibẹ eyi ko di itẹsiwaju ajọ naa lọwọ.

"Idaduro ranpẹ nisẹlẹ yii jẹ fun ajọ yii sugbọn kii se opin irinajo fun wa nitori o ti fi orukọ silẹ pẹlu ileesẹ to n risi eto iforukọsilẹ awọn ileesẹ lorilẹede Naijiria.

"Nitorinaa ko si ibẹru fun awọn ọmọ ajọ yii."