WHO: Naijiria n koju itankalẹ Lassa to ti i l'agbara ju

Eku meji n jẹ eerun ounjẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Minisita feto ilera ni ajumọse ni igbesẹ lati gbogun ti iba ọrẹrẹ

Akọsilẹ ti ajọ to n ṣ'amojuto aarun ni Naijiria fi sita lọsẹ yii ti jẹ ko di mimọ pe okoolelọọdunrun din mẹta eeyan l'ayẹwo ti fidirẹmulẹ pe o ni aisan iba lassa, gẹgẹ bi

Bi o tilẹjẹ wipe igba akọkọ kọ niyi ti aisan naa yoo bu jade ni Naijiria, ṣugbọn ko ti lagbara to bayi ri.

Iye awọn ti wọn fidirẹmulẹ nipasẹ ayẹwo lati bi osu meji si asiko yii pọ ju iye awọn ti akọsilẹ wa fun ni 2017.

Ipinlẹ mejidinlogun ni itankalẹ aisan naa ti de lati igba to ti bujade lọjọ kinni, osu kinni 2018, eyi to yọri si iku eniyan mejilelaadọrin latipasẹ iba to mu ki ẹjẹ maa da lara wọn.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Awọn eniyan marundinlaadọta ti salaisi latari arun iba-pọnju, pọntọ.

Ẹgbẹrun meji ati ẹgbẹrin le marundinlaadọta ni apapọ awọn eniyan to ti ni ifarakanra pẹlu awọn to ni aisan naa, tawọn naa si ti wa labẹ amojuto.

Ajọ WHO n sẹ iranlọwọ fun akitiyanidoola ti ajọ NCDC n dari, pẹlu afojusun lati seto irolagbara fun amojuto, ifimu finlẹ, ayẹwo, to fi mọ amojuto awọn alaisan ati ikopa awọn araalu.

Bakaana ni awọn alaṣẹ eto ilera nipinlẹ naa n ko awọn dokita ati nọọsi lọ si awọn ibudo ti wọn ti n tọju iba lassa.

Aṣoju ajọ WHO ni Naijiria, Dokita Wondimagegnehu Alemu ni "titete da awọn ti o ni aisan naa mọ laarin ilu, to fi mọ gbigbe wọn lọ s'ileewosan lasiko to yẹ maa n mu ki o rọrun lati le doola ẹmi alaisan."

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn eku maa n ko arun iba orere ran gaari

Nipataki julọ, ko si agbara fun awọn ileewosan to wa awọn ipinlẹ Edo, Ondo ati Ebonyi.

Nibayi, ajọ WHO n ṣiṣẹ pẹlu awọn alaṣẹ eto ilera, to fi mọ ileewosan nlanla ati ajọ Alliance for International Medical Action (ALIMA) lati le tete ṣe afikun si awọn ibudo itọju, ati lati pese awọn irinṣẹ ti wọn nilo fun amojuto awọn alaisan, to fi mọ mimu adinku ba ewu to wa fun awọn oṣiṣẹ eto ilera.

Lara awọn to fi ara gba ninu aisan naa ni awọn oṣiṣẹ eto ilera mẹrinla, ninu eyi ti mẹẹrin ti j'ọlọrun nipe.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: