Rwanda ti ṣọọsi 700 pa lori ẹsun aṣemaṣe

ile ijosin kan ni Rwanda

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Rwanda ti ṣọọsi 700 pa lori ẹsun aṣemaṣe

Awọn alasẹ orileede Rwanda ti gbelẹkun awọn ṣọọṣi to le ni ẹẹdẹgbẹrin ti panilu Kigali to jẹ olu-ilu orilẹede naa nitori wipe wọn ko koju oṣuwọn to lori ilana eto aabo ati ilera tijọba la silẹ fun wọn.

Iwe iroyin The New Times to jẹ aladani jabọ iroyin pe ọsẹ to lọ ni igbesẹ naa bẹrẹ, to si jẹ wipe ẹẹdẹgbẹrin le mẹrinla ṣọọsi ati mọsalaasi kan lo ti faragba ninu igbesẹ naa.

Oṣiṣẹ ilu kan, Justus Kangwagye sọ fun iwe iroyin naa wipe awọn ileejọsin naa tapa si ofin eto aabo.

O ni "ijọsin gbọdọ jẹ sise ni ọna to bojumu, to si wa ni tẹle awọn ilana ti wọn lakalẹ. Lilo ominira rẹ lati jọsin ko gbọdọ tẹ ẹtọ ẹlomiran loju mọlẹ.

A ti sọ fun wọn lati dawọ ijọsin wọn duro titi ti wọn o fi koju osuwọn.

Ẹwẹ, o ni awọn ṣọọṣi kan o ti sọ iwe aṣẹ wọn d'ọtun, ati wipe awọn alaṣẹ o ni faaye gba wọn lati maa ba iṣẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn olugbe ilu Kigali gẹgẹ bi iroyin naa ṣe sọ, tako erongba wọn lori igbesẹ naa

Iroyin naa ni awọn ṣọọṣi kan n ṣesin labẹ atibaba, ti wọn o si tun ni ibudo igbọkọ si to to fun awọn olujọsin, eyi ti o maa n mu ki wọn o wa ọkọ wọn gunlẹ si ẹgbẹ ọna, teyi si maa n fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ.

Awọn olugbe ilu Kigali gẹgẹ bi iroyin naa ṣe sọ, tako erongba wọn lori igbesẹ naa.

Awọn kan lara wọn faramọ, nigba ti awọn kan si kesi ijọba lati fun awọn ṣọọṣi naa ni asiko si lati tẹle awọn ilana naa.

Iroyin naa fidirẹmulẹ pe Biṣọọbu Innocent Nzeyimana, aarẹ fẹgbẹ awọn ṣọọṣi to wa l'ẹkun Nyarugenge gbẹnu awọn ṣọọṣi naa sọrọ lati rawọ ẹbẹ pe ki wọn o fun awọn ni anfaani lati maa jọsin titi ti wọn o fi yanju awọn ohun to yẹ lati ṣe.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: