Buhari: Awujọ agbaye yoo kabamọ ti adagun Chad ba gbẹ

Adagun odo Chad Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Orilẹede maarun lo yi adagun odo Chad ka

Aarẹ Naijiria, Muhammadu Buhari ti ṣekilọ pe gbogbo agbaye ni yoo faragba kọja aala ti adagun odo Chad ba fi gbẹ.

Bẹẹ si ni bi adagun odo Chad ṣe n gbẹ, ti mu ki ọpọlọpọ eniyan wa ninu ebi.

Buhari sọrọ naa nibi ijiroro to waye nilu Abuja lori ọna lati doola adagun odo Chad kuro loju ọna iparun.

Adagun odo Chad, laisi aniani n gbẹ loju gbogbo eniyan: pẹlu bi fifẹ rẹ ti ṣe dinku pẹlu ida aadọrun lati bi ogoji ọdun.

Eyi ni wọn ni ko ṣẹyin ayipada oju ọjọ ati aisi amojuto to peye

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọ awọn agbẹ ati apẹja lo ti sa kuro lagbegbe adagun odo Chad nitori pe o n gbẹ

Adagun odo naa ni orisun omi gboogi fun eeyan toto milliọnu lọna ogoji ni pataki julọ ni Naijiria, Chad ati Cameroon.

Ṣugbọn bo ṣe n gbẹ, ti ebi si n pọ si, ni ẹkun naa nsọ agbara nu.

Bawọn eeyan se n kuro nibi kan lati lọ gbe nibomi ti pọ si nitori bawọn agbẹ ati apẹja ṣe n koju ikore ti ko to nnkan, tawọn darandaran naa si n ko jade lati wa omi ati ounjẹ fun awọn ẹran ọsin wọn.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Ikọ Boko Haram naa ti foju sun awọn agbẹ alarojẹ atawọn apẹja lati lo wọn fawọn ipo to ṣofo ninu ẹgbẹ naa.

Awọn olori atawọn aṣoju lati awọn orilẹede to le ni ọgbọn lo ti darapọ mọ aarẹ Buhari nibi ipade apero naa tajọ Unesco nṣatilẹyin fun.

Lopin ipade apero naa loni, awọn olori naa yoo fẹnuko lori boya awọn ọna abayọ to wa nilẹ lati doola adagun odo naa, ati lati sọ di ibi ti yoo ṣee gbe pada, yoo so eso rere, ati boya agbara osẹlu toto wa lati ṣe e.